Peter Gregory Obi (19 July, 1961) je oloselu omo ile Naijiria, ohun si Gomina Ipinle Anambra laarin odun 2006 si odun 2014. O je omo egbe oloselu APGA ati People's Democratic Party(PDP) teleri. O fi egbe oselu PDP kalè ní May 2022 láti darapo mó egbe Labour Party(LA).[1] Ni osu kanáà ni ódi oludije ipò àárè Naijiria ninú lábé egbé oselu Labour Party ni idibo ààre tó ún bo lodun 2023.
[2]
Ìpìlè Àti Èkó Rè
A bí Peter Obi si Onitsha ni 19 July, 1961. O lo ilé-ìwé sekondiri rè ní ilé-ìwé Christ The King College ni Onitsha.[3] Ni odun 1980, a gbàá sile ìwé Yunifásitì ti Nàìjíríà, Nsukka, ósì gba àmì-èye nínú ìmò philosophy ní odun 1984.[4] O padà lo ilé-ìwé onisowo ti Èkó
Ki o to wo oselu
Peter Obi je onisowo okunrin koto dipe ó wo oselu,[5] Obi sope a bi oun sínú idile olutaja, òun náà si ún taja koto dipé obere sí ún sisé ní àwon ilé-isé, ó di ipo adari mu ní àwon ilé-isé bi: Next International Nigeria Ltd, Chairman and Director of Guardian Express Mortgage Bank Ltd, Guardian Express Bank Plc, Future View Securities Ltd, Paymaster Nigeria Ltd, Chams Nigeria Ltd, Data Corp Ltd and Card Centre Ltd., òun ni èni to kéré jù ninú àwon to ti je alaga ilé ifowopamo Fidelity ri.[6]
Òsèlú
Ni odun 2003, Obi díje fún ipò Gomina ìpínlè Anambra sùgbón o fìdíremi fún alatako rè, Chris Ngige, èni tí o jé oludije lábé egbé oselu People's Democratic Party(PDP), Obi gbé oro náà lo ilé ejó Court of appeal, nibi ti wón ti rojo oro náà fun odun meta koto dipe wón yo Chris Ngige nípò lati gbe Obi wolé ní osu Keta, odun 2006,, ni osu Kokanla odun 2006, àwon omo egbé ìgbìmò asofin ti ìpínlè Anambra yo Obi nípò gomina, wón si fi igba kejì rè, Virginia Etiaba sípò Gomina, èyi mú kí Virginia jé Gomina obinrin àkókò ni orílè-èdè Nàìjíríà.[7]Ilé ejó Court of Appeal tún da Peter Obi padà sipo Gomina, Virginia da agbara padà fún Peter Obi léyìn idajo ile ejó.[8]
Ni osù karun 2007, Peter Obi tún fi ipò Gomina sílè léyìn tí Andy Uba wolé gegebi Gomina ìpínlè Anambra, o tori oro yìí lo ilé ejo lekansi, o ni sáà ijoba rè to ye kó bèrè bi odun 2003 kí o sì pari ni odún 2007 bèrè ní odun 2006, nitori náà, kí ilé ejó jé kí sáà ìjoba rè di odún 2010(kí ó ba le lo odún merin ìjoba rè pé). Ilé ejó ti Supreme Court ti Nàìjíríà fi ase sí òrò yìí, èyi tí o mu kí a yo Andy Uba kuro nípò Gomina Anambra
Ni ojo keje, osù kejì, odun 2010(7 Feb 2010), àjo INEC(Independent National Electoral Commission) kéde Peter Obi gegebi olùjáwé olúborí fún ipò Gomina ninú idibo odun 2010. Èyí mú kí Obi lo odún merin si nípò Gomina Anambra.[9] Ni ojo 17 March 2014, Obi fi ipò Gomina kalè, Willie Obiano sì di Gomina ìpínlè Anambra nigbana.
Léyìn idibo gbogbogbo ti odún 2015, Ààré Goodluck Jonathan yan Peter Obi sípò alaga Nigerian Security and Exchange Commission(SEC).[10]
Idibo gbogbogbo odun 2019
Ni 12 October 2018, a yan Peter Obi gegebi ígbákejì oludije Atiku Abubakar, Atiku Abubakar jé olúdíje fún ipò ààré lábé egbé oselu People Democratic Party. Egbe oselu PDP gbé ipò keji ninú idibo gbogbogbo 2019.[11]
Idibo gbogbogbo odun 2023
Ni 24 March 2022, Peter Obi kede ète rè láti díje fún ipò àárè lábé egbé oselu PDP sùgbón o padà ya si egbé oselu Labour Party(LP), labe egbé oselu náà ni o ti ún díje fún ipò àárè Nàìjíríà lowolowo.[12]
Igbesi ayé rè
Obi fé Margaret Brown son Obi ní odun 1992, wón bí omo méjì, omokunrin kan àti omobinrin kan. Obi jé omo ìjo Catholic
Àwon Ìtókasí
- ↑ "Peter Obi". Vanguard News. 2022-05-25. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ Adenekan, Samson (2022-05-30). "UPDATED: Peter Obi emerges Labour Party presidential candidate". Premium Times Nigeria - Premium Times - Nigeria's leading online newspaper, delivering breaking news and deep investigative reports from Nigeria. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ Kolesnik, Kay (2018-09-03). "Peter Obi: early years, education, career and family". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ "Peter Obi: A complete profile". Vanguard News. 2018-10-13. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ A, Olumide (2021-10-08). Kemi Filani News https://www.kemifilani.ng/breaking-news/peter-obis-biography-daughter-wife-net-worth. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ "Managing recession: The Duke, Obi examples". The Sun Nigeria. 2016-10-11. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ "Nigeria's Anambra replaces impeached governor". The Mail & Guardian. 2006-11-03. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ Reporters, Sahara (2007-02-08). "Peter Obi wins, he takes over!". Sahara Reporters. Retrieved 2022-06-29.
- ↑ "THISDAY ONLINE / Nigeria news / African views on global news". thisdayonline.com. 2010-02-12. Archived from the original on 2010-02-12. Retrieved 2022-07-15.
- ↑ Olajide, Bukky (2015-04-28). "Jonathan appoints Peter Obi chairman of SEC - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2020-10-23. Retrieved 2022-07-15.
- ↑ Polycarp, Nwafor (2018-10-12). "Breaking: Atiku picks Peter Obi as running mate". Vanguard News. Archived from the original on 2018-10-13. Retrieved 2022-07-15.
- ↑ Ugwu, Chinagorom (2022-03-24). "2023: Peter Obi declares for president, vows to create jobs, secure Nigeria". Premium Times Nigeria - Premium Times - Nigeria's leading online newspaper, delivering breaking news and deep investigative reports from Nigeria. Retrieved 2022-07-15.