Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà tàbì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà lásán ni olórí orílẹ̀-èdè àti olórí ìjọba Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.[2] Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà náà tún ni Aláṣẹ pátápátáàwọn ológun Nàìjíríà. Àwọn ará Nàìjíríà ún dìbò yan ààrẹ fún ọdún mẹ́rin. Àwọn ipò ààrẹ, àwọn agbára, àti àwọn oyè olórí orílẹ̀-èdè àti olórí ìjọba jẹ́ dídàpọ̀ sí ipò ààrẹ lábẹ́ Òfin-Ibágbépọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà odún 1979. Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, Bola Tinubu, bọ́ sí orí àga ní 29, osù karùn, o̩dún 2023, gẹ́gẹ́bí ààrẹ 16k Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.[3]
↑ 4.04.1"Nnamdi Azikiwe - Biography & Facts". Encyclopedia Britannica. 1998-07-20. Retrieved 2023-06-12.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "Encyclopedia Britannica 1998" defined multiple times with different content