Orile-ede Sahrawi Arabu Olominira Toseluarailu (SADR) (Lárúbáwá: الجمهورية العربية الصحراوية الديمقراطية, Spánì: [República Árabe Saharaui Democrática] error: {{lang}}: text has italic markup (help)) je orile-ede ti awon die gba to fowogbaya lori gbogo agbegbe Apailaorun Sahara, amusin ile Spein tele. SADR je lilasile latowo Polisario Front ni February 27, 1976. Ijoba SADR lowolowo n joba lori agbegbe bi 20% to fowogbaya fun. O pe awon agbegbe to wa labe ijoba re ni "Agbegbe Ominira" tabi "Aaye Ainidekun." Orile-ede Morocco lo n sejoba awon agbegbe yioku to si pe ibe ni igberiko Apaguusu. Ijoba SADR gba pe awon agbegbe to wa labe ijoba orile-ede Moroko je "Agbegbe Idurolelori (Occupied Territory) " nigbati Moroko gba pe agbegbe kekere to wa labe SADR je "Aaye Idasi (Buffer Zone)."
Itokasi