Àngólà, lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Àngólà (Pọrtugí: República de Angola, pípè [ʁɨˈpublikɐ dɨ ɐ̃ˈɡɔla];[4] Kikongo, Kimbundu, Umbundu: Repubilika ya Ngola), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní apágúsù Áfríkà tó ní bodè mọ́ Namibia ní gúsù, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò ní àríwá, àti Zambia ní ilàòrùn; ìwọ̀òrùn rẹ̀ bọ́ sí etí Òkun Atlántíkì. Luanda ni olúìlú rẹ̀. Ìgbèríko òde Kàbíndà ní bodè mọ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Kóngò àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò.
Àngólà di ileamusin Portugal ni 1884 leyin Ipade Berlin. O gba ilominira ni odun 1975 leyin ogun itusile. Ko pe leyin ilominira ni ogun abele sele lati 1975 de 2002. Àngólà ni opo alumoni ati petroliomu, be sini okowo re ti ungbera soke pelu iwon eyoika meji lati odun 1990, agaga lateyin igba ti ogun abele wa sopin. Sibesibe opagun ijaye si kere gidigidi fun opo alabugbe, be sini ojo ori ati iye ọ̀fọ̀ ọmọwọ́ ni Angola je awon eyi to buru julo lagbaye.[5]
Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ.