Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ owó náírà ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 1973,[5] wọ́n pààrọ̀ owó Pọ́nhùn Nàìjíríà tí Nàìjíríà ń lò tẹ́lẹ̀. Owó yìí ni Pọ́nhùn kan(£1) tí a ṣe sí náírà meji.[6] Owó tuntun náà jẹ́ owó àkọ́kọ́ tí Nàìjíríà ṣe jáde lẹ́yìn òmìnira Nàìjíríà. Owó tí Nàìjíríà ń lò kí ó tó di ìgbà náà ni Pọ́nhùn Nàìjíríà tí ìjọba a kọ́ni lẹ́rú Naijiria ṣe ní ọdun 1959, tí orúkọ Èlísábẹ́tì kejì sì wà lára rẹ̀.[7]
Obafemi Awolowo lọ́ mú abá orúkọ "Náírà" wá, ó yọọ́ lára "Nàìjíríà" [8][9] ṣùgbọ́n , mínísítà tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó, Shehu Shagari ni ó gbé owó náà síta ní ọdun 1973.
Central Bank ti Nigeria sọ pé wọ́n gbìyànjú láti ṣàkóso àfikún ọdọọdún kí ó wá sílẹ̀ sí ìdá mẹ́wàá. Ní ọdún 2011, CBN fi kún owó-èlé ní ìlọ́po mẹ́fà, ó gòkè si láti 6.25% sí 12%. Ní ọjọ́ kkalnlélọ́gbọ̀n oṣù kìíní, ọdún 2012, CBN pinnu láti ṣètójú owó-èlé náà kí ó ba lè wà ní 12% àti pé kí àfikún sí oẃ níná ba lè díkù.[10]
Ní ọjọ́ ogún oṣù kẹfà, ọdún 2016, náírà nih àǹfààní láti léfòó, lẹ́yìn tó tí wọ́n ti fi sí àhámọ́ ní ₦197 sí US$1 fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.
Wàhálà tó wáyé látàrí owó Nàìjíríà tuntun ṣẹlẹ̀ lójijì ní oṣù kejì ní ọdún 2023 nítorí àìtó náírà àti ìgbìyànjú àwọn ìjọba láti mú kí àwọn ará-ìlú fi tipátipá ná owó tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ gbé jáde. Èyí sì já sí ìfi-ẹ̀họ́nú-hàn káàkiri àdúgbò ní àárín oṣù lejì, ní ọdún 2023.[11][12][13]
Coins
Ní ọdún 1973, wọ́n gbé kọ́ìnsì wọlé, a sì ní kọ́ìnsì ní kọ́bọ̀ 1⁄2, 1, 5, 10 àti 25. Kọ́ìnsì 1⁄2 àti 1 ní wọ́n ṣe p̀lú idẹ, wọ́n sì fi kọ́pà ṣe àwọn owó ńlá. Àwọn kọ́ìnsì kọ́bọ̀ 1⁄2 ní wọ́n ṣe sí pẹ́pà ní ọdún náà. Ní ọdún 1991, àwọn kọ́ìnsì kékèèké bíi kọ́bọ̀ 1, 10 àti 25 ni wọ́n ṣe pẹ̀lú kọ́pà àti irin. Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2007, wọ́n ṣe àwọn kọ́ìnsì tuntun síta bíi kọ́bọ̀ 50, ₦1 àti ₦2.[14]
Ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, ọdún 1973, Central Bank ti Nàìjíríà gbé kọ́bọ̀ 50, ₦1, ₦5, ₦10 àti ₦20 jáde sínú pẹ́pà: ní oṣù kẹrin ọdún 1984, wọ́n yí àwọn àwọ̀ orí owó náírà wa padà lahti dẹ́kun kíkó owó jẹ́.[23] Ní ọdún 1991, wọ́n tẹ ₦50 jáde, wọ́n si fi kọ́ìnsìn dípò kọ́bọ̀ 50 kobo àti ₦1 ní ọdún 1991. Èyí sì tẹ̀lé ₦100 ní ọdún 1999, ₦200 ní 2000, ₦500 ní 2001 àti ₦1,000 ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹwàá, ọdún 2005.[24]
Ní oṣụ̀ kejì, ọdún 2007, àwọn ẹ̀yà tuntun fún ₦5 sí ₦50 bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde. Ní àárín ọdún 2009 nígbà tí Sanusi Lamido Sanusi di Gómìnà CBN,[25] wọ́n ṣèyípadà àwọn ₦5, ₦10 àti ₦50 sí owó náílọ̀n.
Lórih owó ₦1,000, wọ́n ṣe kiní kan si lẹ́yìn láti má fàyè ayédèrú. Àwọn àbùdá àdámọ́ ara owó náà ni àwòrán Alhaji Aliyu Mai-Bornu àti Dr. Clement Isong, tí wọ́n jọ fìgbà kan jẹ́ gómìnà CBN.[26]
Lórí ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe fún ₦100 ní ọjọ́ kìíní oṣù kejìlá, ọdún 1999, àwòrán àpáta Zuma, èyí tí wọ́n sọ pé ó wà ní Agbègbè Olú-ìlú Ìjọba Àpapọ̀ Nàíjíríà lára owó náà, àmọ́ Ìpínlẹ̀ Niger gan-an ni ó wà. Wọ́n padà yọ ìtọ́ka pé Abuja ni àpáta yìí wà kúrò lára owó náà.[27]
Ní ọdún 2012, CBN gbèrò láti ṣàtẹ̀jáde owó tuntun fún ₦5,000. Ilé-ìfowópamọ́ náà tún pinnu láti ṣèyípadà ₦5, ₦10, ₦20 àti ₦50 sí kọ́ìnsìn tó ti padà di ìwé báyìí.[28]
Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kọkànlá, ọdún 2014, Central Bank of Nigeria gbèrò láti ṣàtúnṣe sí ₦100 ṣàjọyọ̀ ìdásílẹ̀ Nàìjíríà fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Owó àtijọ́ àti tuntun jọra pẹ̀lú àwòrán Olóyè Obafemi Awolowo tó wà níwájú rẹ̀, àtúnṣe tó kọ̀ wà níbè ni àwọ̀ tí wọ́n pààrọ̀, àti àkọsílẹ̀ "One Nigeria, Great Promise". Lẹ́yìn owó tuntun náà ó ní kiní kékeré kan tí ènìyàn le síkàànì tí á sì gbé wa lọ sí àyọka tí wọ́n kọ lórí ìtàn Nàìjíríà.[29][30]
Ní ọdún 2019, ₦100 gba àbùdá àdámọ̀ tuntun nígbà tí ìbọwọ́lùwé Priscilla Ekwere Eleje, tó jé Director of Currency operations fún Central Bank of Nigeria, tó sì tún jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ wà nípò náà.[31]