Abubakar Bukola Saraki, MBBS, Àdàkọ:Post-nominals (ojọ́ ìbí rẹ̀ ni ni ọjọ kọkandinlógún, osù kọkànlá, ọdún 1962) jẹ́ olósèlú kan ní ilé Nàìjíría. Ó jẹ́ Ààrẹ Ketàlá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílé èdè Nàìjíríà láti ọdún 2015-2019, àti pé òun náà ni Ààre kẹjọ fún ilé ìgbìmò asòfin ní orílé Èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó jẹ́ Gómìnà ní ìpínlè Kwara láti ọdún 2003 títí dé 2011 lábé àwọn ọmọ ẹgbẹ PDP ( People Democractic Party)[3][4] ó sì tún jẹ́ aṣojú Central Senatorial District tí ìpínlẹ̀ Kwara ní láàrin ọdún 2011 sí 2019, ó lọ ṣáà àkókò lábẹ́ abé ẹgbẹ́ òsèlú People Democratic Party àti ṣáà kejì lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú All Progressive Congress.[5][6][7]
Ní ọjọ tí o gbẹ̀yìn oṣù keje ọdún 2018, Ní Sàràki kúrò ní Ẹgbẹ́ APC, tí ó sì padà sí ẹgbẹ́ PDP ti ó wà ní àkọkọ́, tí ó fí dì ààrẹ ẹgbẹ́ alátàkò .[8][9][10] Sàràki kéde pé òun yóò wà lára àwọn tí wọn sára fún Ìpo ààrẹ Orile èdè Nàìjíríà, tí o sí rà iwe tí wọn ń pé ní Presidential Ticket ní ìdìbò ọdún 2019,[11]amò nínú ìbò abẹlé, ó fi ẹ̀yin lè lẹ nígbà tí Atiku Abubakar jáwé olúborí. Amò ó tún tẹ̀síwájú láti kéde pé òun ní Olùdarí Àgbà ẹgbẹ́ tí ó ń ṣètò ìponlogo fún Atiku Abubakar tí n du ipò ààrẹ ní idibo gbogbogboo ni ọdún 2019, sùgbóọ́n òun náà fẹ̀hìn lè lẹ nígbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari jáwé olúborí tí ó pàdé dì ààrẹ fún orílé Èdè Nàìjíríà.[12][13]
Ìdílé
Wọn bí Saraki ni ọjọ kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ní ọdún 1962 ní Lọ́ǹdònù[14] tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Florence Morenike Sàràki àti bàbá rẹ̀ Olusola Saraki, tí òun náà nígbà kan rí tí jẹ́ Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní orílé èdè Nàìjíríà.[15] Bukola Saraki fẹ Toyin Saraki (née Ojora), tí wọn sì jọ bí ọmọ Mẹ́rin.[16]
Ètò Ẹkọ
Sàràki jáde ní ilé ìwé Ẹkọ gíga King's College, ni Lagos, níbi tí o tí jáde ní ọdún 1978. Ó kúrò níbẹ ó lọ sí Cheltenham College, èyí tí o jẹ́ ilé ìwé (boarding school) ni United Kingdom láti 1979 titi dé 1981. Tí o túnbọ̀ tẹsiwaju láti lọ kàwé sí ní Fásitì tí wá ní London ni ilé ìwòsan tí London Medical college láti ọdún 1982 tí tí dì 1987 ní bí tí o tí kàwé gbọyè Bachelor of Medicine, Bachelor of Surgery.[17]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀ Iṣé Ṣiṣe
Saraki ṣíṣe ní ilé ìwòsan Rush Green ni Essex gẹ́gẹ́ ní Oníwòsàn ní ọdún 1988 sí òdun 1989. Saraki tun je Olùdarí ilé iṣẹ ìfowópamọ́si ní orílé Èdè Nàìjíríà tí orúkọ ilé ìfowópamọ́si náà sì ń jẹ Société Générale (Nig) Ltd láti ọdún 1990 si 2000.[18] ní ọdún 2000, Ààrẹ Olusẹgun Õbásanjọ́ fí Saraki jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí ààrẹ lórí bí àṣẹ ń náwó.[19][20]