Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da Ìpínlẹ̀ Ògùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 1976. Ìpínlẹ̀ Ògùn fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Èkó lápá Gúúsù, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lápá Àríwá, Ìpínlẹ̀ Òndó àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin lápá Ìwọ̀-Oòrùn. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Ọmọọba Dapo Abiodun tí wọ́n dìbò yàn-án wọlé lọ́dún 2019 fun ìgbà àkokò re, wón si tun dibò yàn án nì èkeji nì òdún 2023. Abẹ́òkúta ni olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìlú tí ó ní ọ̀pọ̀ olùgbé jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà. Méjì lára àwọn ìlú mìíràn tí ó ṣe pàtàkì ni Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ìjẹ̀bú-Òde, olú-ìlú ọba aládé tí Ìjẹ̀bú Kingdom fún ìgbà kàn rí àti Sagamu, ìlú tí ń ṣe aṣáájú níbi ká gbin obì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tó ń ṣe agbátẹrù ètò ọrọ̀ ajé tó múnádóko. Orúkọ ìnagijẹ ìpìnlẹ̀ Ògùn ni the Gateway State.
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn
Ìjọba ìbílẹ̀ ogún ló wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, àwọn sì ni:
Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilé-ìwé ìjọba àpapọ̀ mẹ́ta, àwọn ni; Federal Government Girls' College, Sagamu[3] àti Federal Government College, Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odogbolu[4] àti Federal Science and Technical College, Ijebu-Imushin.[5]
Bilikisu Sungbo Shrine, ní Oke-Eiri, lágbègbè Ijebu-Ode. Ibí yìí ní àwọn Ijebu gbàgbọ́ pé wọ́n sin [15]Queen of Sheba tí wọ́n tún máa ń pè ní Bilikisu alága Wúrà. Ó jẹ́ ibi ọ̀wọ̀ àti ààyè tí àwọn oníṣẹ̀ṣe yà sọ́tọ̀. Àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́ẹ́nì ló máa ń lọ ibẹ̀.
Ìpínlẹ̀ Ògún jẹ́ dídílẹ̀ láti ọwọ́ ìjọba Murtala/Ọbásanjọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejì, ọdún 1976 látara níhàa Ìwọ̀-Oòrùn àtijọ́. Wọ́n sọ ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn odò Ògùn, tí odò náà ṣàn káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti Àríwá lọ sí Gúúsù. Ìpínlẹ̀ náà ní àyíká ìgbìmọ̀ ìjọba agbègbè ogún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọwọ́ ajẹmọ́-ìran mẹ́fà tó tóbi, àwọn náà ni: Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Rẹ́mo, Ẹgbádọ̀, Àwọrí àti Ègùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn kékeré mìíràn wà bí Ìkálẹ̀, Kẹ́tu, Ohori àti Anago.[16] Ìwé- ìpamọ́ jẹ́ẹ̀rí pé ìpínlẹ̀ yìí ló ní Fáṣítì Àdáni àti ilé-ìwé gíga ní Nàìjíríà àti ìpínlẹ̀ tó ní Fáṣítì ìpínlẹ̀ ara rẹ̀ méjì ni Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ògùn tún jẹ́ ilé fún Fáṣítì fún Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ àti ìgbẹ̀yìn.[17][18]
Ìpínlẹ̀ Ògùn tí pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ìjọba ní Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn. Gbogbo àwọn ara Gúúsù Ìwọ̀-Oòrùn tó ti jẹ Ààrẹ tàbí olórí ìpínlẹ̀ fún ìlú wá láti ìpínlẹ̀ Ògùn (Ọbásanjọ́, Shónẹ́kàn) wọ́n gba oríyìn láti ìpínlẹ̀ Ògùn. Olóyè Jeremiah Ọbáfẹ́mi Àwọ́lọ́wọ̀, Olórí àkọ́kọ́ fún Agbègbè Ìwọ̀-oòrùn, ó dẹ̀ jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn ará Ìjẹ̀bú ní ìpínlè yìí ni àwọn Yóò á àkọ́kọ́ tó nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Europe ní ṣẹ́ńtíúrì kẹrìnlá. Àwọn ènìyàn náà tún gbà wí pé àwọn ni ẹ̀yà Yoòbá tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ma lọ owó tí a mọ̀ sí owó-Ẹyọ, tí ó jẹ́ àtawọ́gbà ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá kí wọ́n tí rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ìsì nígbà tí àwọn Europe dẹ́.[19]
Àtòjọ àwọn ènìyàn tó lààmìlaaka tó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ yìí