Oruko re bi "Brasil" wa lati oruko igi brasil, igi kan to n wu nigbakan ni janti rere leti eba omi Brasil. Ni ede Portugal, igi brasil unje pau-brasil, nibi ti brasil ti tumo si "pupa bi ojuina", lati ede Latinbrasa ("ember") ati alemeyin -il (lati -iculum tabi -ilium).[19][20][21] Nitoripe igi brasil se da aro pupa, o niyi daada ni Europe lati fi kun aso, ohun si ni aje akoko to wulo lati Brasil. Kakiri igba orundun 16k, opo igi brasil je fifatu latowo awon eniya abinibi (agaga awon Tupi) leba etiomi Brasil, awon yi si ta won fun awon onibukata ara Europe (agaga awon ara Portugal, ati fun awon ara Fransi) fun pasiparo fun orisi oja amulo lati Europe.[22]
Oruko onibise ile yi, ninu awon akosile awon ara portugal, je was the "Ile Agbelebu Mimo" ("Land of the Holy Cross"; Terra da Santa Cruz), sugbon awon awako-ojuomi ati oloja ara Europe unsaba pe lasan bi "Ile Brasil" ("Land of Brazil"; Terra do Brasil) nitori bukata igi brasil. Oruko yi lo gbajumo titi do ni to fi ropo oruko onibise. Bakanna awon awako ojuomi nibere pe ibe ni "Ïle àwon Odidere" ("Land of Parrots"; Terra di Papaga).
Ni ede Guarani, ti se ede onibise kan ni Paraguay, Brasil unje pipe ni "Pindorama". Oruko yi ni awon eniyan abinibi fun agbegbe yi, itumo re ni "ile awon igi ọ̀pẹ" ("land of the palm trees").
Ori ile ti a mo loni bi Brasil je gbigbesele latowo Portugal ni April 1500, nigba ti oko-ojuomi lati Portugal ti Pedro Álvares Cabral dari gunle.[23] Awon wonyi pade awon are ibe ti ede opo won je ti Tupi–Guarani. Botilejepe ilu abudo akoko je didasile ni 1532, imusin ko bere titi to fi di 1534, nigbati Oba DomJoão 3k ile Portugal pin ibe si ile basorun ajogun mejila.[24][25]
Eto yi ko ni yori i rere rara, bosi ti di odun 1549 oba yan Gomina Agba kan lati samojuto gbogbo ibe.[25][26] Awon eya abinibi bi melo kan je fifamora,[27] awon miran je kikoleru tabi piparun ninu ogun tabi pelu awon arun ti awon ara Europe ko ran won ti ara won ko ni ajesara si.[28][29] Nigba ti yio fi di arin orundun 16k, suga ti di oja okere pataki fun Brasil[30][31] nitori awon ara Portugal yi ko opo eru wa lati Afrika[32][33] lati fi won sise fun ibere oja suga to unpo si kariaye.[28][34]
Nipa gbigbogun ti awon ara Fransi, awon ara Portugal diedie fe ile won de guusuilaorun, won si gbesele ilu Rio de Janeiro ni 1567, ati de ariwaiwoorun, nibi ti won ti gbesele ilu São Luís ni 1615.[35] Won ran awon ologun losi igbo-aginju Amasoni won si bori awon ajagun Britani ati Holandi to wa nibe,[36] ki won o to bere sini da abule ati ile ologun sibe lati 1669.[37] Ni 1680 won de guusu nibi ti won da Sacramento sile si ni eba Rio de la Plata, ni agbegbe Etiomi Apailaorun region.[38]
Ni opin orundun 17k, oja suga ni okere bere si ni re sile[39] sugbon lati ibere awon odun 1690, iwari wura latowo awon oluwakiri ni agbegbe na to unje pipe ni Minas Gerais ni Mato Grosso ati Goiás loni, gba ibi amusin na la lowo iparun.[40] Kakiri lati Brasil, ati lati Portugal, egbeegberun eniyan tu wa si koto alumoni lati wa sise.[41] Awon ara Spein gbira lati dena awon ara Portugal lati fe ile won de ori ile to je ti won gegebi Adehun Tordesillas 1494, won si yori lati gbesele Etiomi apailaorun ni 1777. Sibesibe, asan ni eyi jasi gegebi Adehun San Ildefonso, ti won fowosi lodun kanna yi, sedaju ase Portugal lori gbogbo awon ile ti won ba gbesele, ati igba yi ni opo gbogbo bode Brasil loni ti wa.[42]