Argẹntínà Nínú ètò ìkànìyàn 1995, iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà (Argentiana) lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì àti àti ààbọ̀ (46 245 668). Èdè Pànyán-àn ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní orílè-èdè yìí lé ní ogún. Lára àwọn ogún èdè yìí ni àwọn èdẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Àmẹ́rídíánà (Ameridian Languages) wà. Ara àwọn èdè.
Àmérídíánà yìí ni ‘Guarani, Araucanian, Metaco àti Quechua’.
Àwọn èdè tí ó tún wà lára ogún yìí ni èdè tí àwọn tí ó wá se àtìpó ń sọ. Lára wọn ni èdè Ítílì (Ìtahàn) àti Jámánì (Herman). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè fún òwò àgbáyé àti èdè àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò wá sí ibẹ̀ (International trade and tourism). Wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí pẹ̀lú èdè Pànyán-àn.
↑Article 35 of the "Constitution"(PDF). Archived from the original(PDF) on 2007-11-22. Retrieved 2009-10-04. gives equal recognition to "United Provinces of the River Plate", "Argentine Republic" and "Argentine Confederation" and authorises the use of "Argentine Nation" in the making and enactment of laws