Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom jẹ́ ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀karùndínlógún ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù márùn-ún-àbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[2]
Ayé òde-òní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ní olùgbé láti bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn tí ó kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ àbátan Ibibio, Anaang, àti Obolo - Oron àwọn ènìyàn ní àríwá-ìlà-oòrùn, àríwá-ìwọ̀-oòrùn, àti agbègbè gúúsù Ìpínlẹ̀ náà, lẹ́sẹsẹ. Ní àkókò ìmúnisìn, Ohun tí a wá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ Akwa Ibom báyìí pín sí oríṣiríṣi ìlú-ìpínlẹ̀ bíi Ibom Kingdom àti Akwa Akpa kí ó tó padà di Ìpínlẹ̀ lẹ́bẹ́ àbò ìjọba aláwọ̀-funfun ní 1884 gẹ́gẹ́ bí apákan Oil Rivers Protectorate.[3]