Ìdìtẹ̀gbàjọba ní Nàìjíríà ọdún 1966 bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kíní, ọdún 1966, nígbà tí àwọn ṣọ́jà tí inú ń bíi Chukwuma Kaduna Nzeogwu àti Emmanuel Ifeajuna tí wọ́n pa ènìyàn méjìlélógún. [2] nínú èyí tí wọ́n pa Mínísítà àgbà fún ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ̀lẹ̀, àwọn olóṣèlú jànkàn jànkàn, àwọn ọ̀gá ṣọ́jà àti àwọn ìyàwó wọn.[3][4] Àwọn adìtẹ̀gbàjọba kọ lu àwọn ìpínlẹ̀ bíi Kaduna, Ibàdàn, àti Èkó, nígbà tí wọ́n dí ojú-ọ̀nà Niger àti Odò Benue odidi ọjọ́ méjì gbáko ṣáájú kí wọ́n tó rí wọn mú. Ọ̀gágun àwọn ọmọ ohun ilẹ̀ nígbà náà, ọ̀gágun Johnson Aguiyi-Ironsi ní láti tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà, tí ìṣàkóso àwọn olóṣèlú sì gbélẹ̀. Gígoróyè Ìrọnsì gorí oyè ni ó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àti àtìlẹyìn àwọn adìtẹ̀gbàjọba gbogbo wọ́n sì jẹ́ ẹ̀yà Ìgbò. Àwọn ṣọ́jà Hausa náà dìtẹ̀ gbàjọba pada tí èyí náà sì já sí ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ṣọ́jà àwọn Igbò, tí èyí sì mú kí ogun abẹ́lé ilẹ̀ Nàìjíríà bẹ́ sílẹ̀.
Àwọn Ìtọ́ka sí