William John Harper (Ọjó kejìlélógún Oṣù keje Ọdún 1916 – Ọjó kẹjọ Oṣù kọkànlá) jẹ́ olóṣèlú, agbaṣẹ́ ṣisẹ́, àtí awakọ̀ òfúrufú ológun Royal Air Force tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ óṣèlú ilẹ̀ Rhodesia láti ọdún 1962 sí 1968 tí ó tọwọ́ bọ ìwé tí ìlú náà fí gba òmìnira lati ọwọ́ Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 1965. Wọ́n bíi sí ìdíilé olókìkí oníṣòwò Calcutta tí apá kan obí rẹ̀ jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì tí ìkan tókù jẹ́Índíà, Harper kàwé ní orílẹ̀ èdè Índíà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti pé ó darapọ̀ mọ́ RFA ní ọdún 1937. Ó jẹ́ ọ̀gágun nígbà ogun àgbáyé kejí, tí ó jẹ́ ìkan lára "Àwọn díẹ̀" ní "Ogun Gẹ̀ẹ́sì", tí wọ́n ti paálára lójú ogun. Ó jẹ́ ìyanu fún n nígbà tí Gẹ̀ẹ́sì fún Índíà lómìnirà ní ọdún 1947, ó kọjá sí Rhodesia lẹ́yìn tí ó fẹ̀yìntì nínú ajagun òfurufú lẹ́yìn ọdún méjì síi.
Harper lòdì sí ìfòpin sí ìjẹgàba Gẹ̀ẹ́sì lórí àwọn orílè èdè tó wà lágèègbè rẹ̀, ó sì dúró lé pé kí ìlú tí wọ́n tí gbààtọ́, orílè èdè Gùùsù Àfíríkà àti agbèègbè Àgùdà wà "wà lábẹ́ ìjọba òyìnbó aláwọ̀ funfun láíláí.
Ó darapọ̀ mọ́ òṣèlú pẹ̀lụ́ egbẹ́ òṣèlú Dominion Party ní ọdún 1958, tí ó sí jẹ mínísítà fún bíbómirìn, pópónàn àti àfúnpọ pópónà ní ìjọba ẹ́gbẹ́ òṣèlú Rhodesian Font (RF) ní ọdún 1962. Ó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ kan nínú RF, ó sọ fún orílẹ̀ èdè Rhodesia wípé kí wọ́n fòpin sí gbígba èèyàn dúdú làyé kí wón ṣe aṣojú ní ilé ìgbìmọ̀, ó sì gba "òṣèlú tí ó dàbí élẹ́yàmẹ̀yà". Nígbà tí alákòóso àgbà Winston Field fipòsílẹ̀ ní ọdún 1964, Harper jẹ́ ìkan gbọ̀n nínú àwọn tó gbìyànjú àtí rọ́pò ẹ̀ lan Smith ló borí tí ó sì fí òhun sí ọfiisi alákòóso fún abẹ́lé.
Gbogbo dídẹnukọlè tàbí ìfàsẹ́yìn tí ó ṣẹlè ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba Smith jẹ́ kí àwọn oní ìwé ìròyìn ròpé Harper ló máa rọ́pò ẹ̀. Ní ọdún 1966, tí Smith gba ìwé iṣé padà lọ́wọ́ HMS Tiger pèlú alákòóso àgbà Gẹ̀ẹ́sì Harold Wilson, Herper ṣiwájú àtako rẹ̀ tí ó sì fa ìkọ̀sílẹ̀. Harper fipòsílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ Rhodesian Front ní ọdún 1968, láìpẹ́ sí ìgbà tí Smith yọó lóyè nítorí wípé Harper yànlè pẹ̀lú òṣìsẹ́ Gẹ̀ẹ́sì kan. Ó padà di ọlọ̀tẹ̀ alákòóso àgbàm, tí ó ń jẹ́ kí gbogbo ìgbìyànjú Smith lati ri pé ìrẹ́pọ wà láàrin àwọn èèyàn dúdú nígbà ogun abẹ́lé ti ilẹ̀ Rhodesi dàbí ohun tí kò dára lójú àwọn ènìyan. Lẹ́yìn ìgbà yìi, òṣèlú aráìlú bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Zimbabwe Rhodesia ní ọdún 1979, lẹ́yìn ìparí ìjà láàrín ara wọn ní ọdun tó kọjá, Harper kọjá sí orílẹ̀ èdè Gùùsù Áfíríkà. Ó kú ní ọdún 2006 lẹ́yìn tí ó lo àádọrún ọdún láyé
Ìgbà èwe
Wọ́n bí William John Harper ní Ọjó kejìlélógún Oṣù keje Ọdún 1916 sí Calcutta, Gẹ̀ẹ́sì Índíà, ìran olókìkí oníṣòwò ìgbà láyé láyé kan tí apá kan obí rẹ̀ jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì tí ìkan tókù jẹ́ Índíà tí ó ń gbé ní ààyè ńlá kan tí ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú East India Company ní ọ̀rúndún méjìdínlógún àti ọ̀kàndínlógún sẹ́yìn. Ó kàwé ní North Point ní Darjeeling, Índíà àti ní Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú Windsor. Ọ́ dàgbà sí ọkùnrin kúkurú tí kò gbàgbàkugbà tí isọ̀rọ̀sí rẹ̀ sì já fáfá. Nathan Shamuyarira kọ nípa rẹ̀ wípé "ẹnu rẹ̀ tó fúnpọ̀ kìí sábà rẹrín, tí ó fi dabí pé ó maa ń fẹ́ bínú ní gbogbo ìgbà
Ogun Àgbáyé Kejí; awakọ̀ òfúrufú ológun Royal Air Force
Harper darapọ̀ mọ́ RFA ní ọdún 1937, ó dí ọ̀gágun fìdíẹ́ awakọ̀ òfúrufú ní Ọjó karún Oṣú kẹsan. [2] Ó ní ìgbéga sí flying officer ní Ọjọ́ kejílá Oṣù kejì ọdún 1940,[3] wọ́n komọ́ No. 17 Sqadron. Ní Ọjọ́ kejìdínlóguń Oṣù karún, ó wà lára àwọ́n tí ó ba Messerschmitt 110 jẹ́, lẹ́yìn ọsẹ̀ kan síi, ó ba Ju 87 "Stuka" dive bomber jẹ́. Wọ́n yàn ní apàṣẹ́ B Flight pẹ̀lú okùn fìdíẹ́ flight lieutenant, ní Ọjọ́ kẹrìndínlógún Oṣú karun. Ó ba Bf 110 míràn jẹ́ lórí Dunkirk ọjọ meta lẹ́yìn ìgbà náà, ti wón lé àwọn ológun kúrò létí òkun nígbà ogun àgbáyé, ó wa ní ipò apàṣẹ́ B Flight yí di Ọjọ́ kẹjọ Oṣù kẹfà ọdún 1940, kí wón tó da padà sí okùn flying officer. Wón tún gbega sí okùn fìdíẹ́ flight lieutenant ní Ọjó kẹrin Oṣù keje, nígbà tí wọ́n fun ní àṣẹ A Flight. Láti Oṣù keje ọdún 1940, ó ṣí ń fò pẹ̀lú No. 17 Squadron, Harper jẹ́ ìkan lára "Àwọn díẹ̀" awakọ̀ òfurufú nígbà "Ogun Gẹ̀ẹ́sì". Ní Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kẹjo ó wà lárà àwọn tó ba Bf 110 àti ohun ìjà Messerchmitt Bf 109 jẹ́. Ọjọ́ kẹrin síi, lẹ́yìn tí wọ́n gbée kúrò gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ Hawker Hurricanes mẹ́fà tí wọ́n ní kí ó lọ dojú kọ ọkọ̀ òfurufú tí ó ju bí ogún, Harper farakan ọkọ̀ òfurufú jámánì nìkan tí ó dàbí wípé ó ba Bf 109 jẹ́ kí ó tó já wálẹ̀. Ó jábọ́ sí pápá kan lẹ̀gbẹ́ Suffolk níìlú Felixstowe, ó di èrò ilé ìwòsán tí ó si fi ojú àti ẹsẹ̀ pa. O padà darapọ̀ mọ́ No. 17 Squadron láìpẹ́ sí tí ó sì tẹ̀síwájú bí apàṣẹ A Flight lati ilẹ̀—Ó padà sókè ní Ọjọ́ kínín Oṣù kọkanlá ọdún 1940. Ọ̀sẹ̀ kan si, ó ba Ju 87 jẹ́ bóyá ó tún ba òmíràn jẹ́. Harper gba okùn flight lieutenant ni Ọjọ́ kejìlá Oṣù kejì ọdún 1941.[4] Lẹ́yìn Oṣù kan, wọ́n gbe lọ sí No. 57 Operational Training Unit RAF, tí ó wà ní RAF Hawarden ní Wales, bíi olùkọ́ni.