Tosin Igho jẹ́ olùdarí fíìmù àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Tosin jẹ́ ọmọ olóòtú ètò NTA tó gbajúmọ̀, tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Peter Igho.[1] Ó gba òye ẹ̀kọ́ nínú ìmọ Visual Effects láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti AFDA ní Cape Town, South Africa tí ó sì tún gba oyè bachelor's degree nínú ìmọ motion picture medium.[2][3] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórin, tí ó sì tún jẹ́ olùdarí àwọn fídíò orin lóríṣíriṣi. Ó ti fìgbà kan jẹ́ olùdarí fídíò orin èyí tí àwọn gbajúmọ̀ olórin bíi Mo' Hits Records' D'banj, Terry G, Faze, Yung L, Aramide àti Sammie Okposo.[4]
Ó jẹ́ aṣàgbéjáde àgbà fún àwọn ètò bíi Once Upon A Time, Judging Matters, Love Come Back (2020-2022), I am Laycon.[2][1]
Ó jẹ́ olùdarí fíìmù Seven (2019), The Eve (2018), Nneka the Pretty Serpent (2020), Team Six (2021), bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣiṣẹ́ lórí fíìmù Suspicion (2023)