Oluwarotimi Odunayo Akeredolu, SAN, or Rotimi Akeredolu, (ọjọ́ ìbí 21 July 1956 - 27 December 2023) jẹ́ olóṣèlú àti agbẹjọ́rò ará Nigeria tó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ Ondo ní orílẹ̀ edè Nàijíríà lọ́wọ́lọ́wọ̣́. [1] Akeredolu tún jẹ́ ìkan nínú àwọn agbẹjọ́rò àgbà ti ilẹ̀ Nàìjíríà (SAN) tí ó sì jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ amòfin ti orílẹ̀ edè Nàijíríà ní ọdún 2008.[2]
Wọ́n bí Akeredolu ní ọjọ́ kọ̀kàn-lé-lógún oṣù keje ọdún 1956 ní Owo sí Reverend J. Ola Akeredolu ti ẹbí Akeredolu àti Lady Evangelist Grace B. Akeredolu ti ẹbí Aderoyiju ti Igbotu, Ese Odo, ní Ìpínlẹ̀ Ondo.
Akeredolu ṣe ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé ìjọba kan ní Ọ̀wọ̀. Ó tẹ̀síwájú láti lọ sí Aquinas College, níAkure, Loyola College ní Ìbàdàn àti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan ní Ayetoro, fún ẹ̀kọ́ ilé-ìwé gíga rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ ilé-ìwé gíga gíga rẹ̀. [3] Orúkọ àárín rẹ̀ "Ọdúnayọ̀" túmọ̀ sí "Year of happiness" ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. [4] Ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ifẹ̀ (tí a mọ̀ sí Obafemi Awolowo University) láti kọ́ ẹ̀kọ́ òfin, tí ó sì ṣe ayẹyẹ ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1977.[5] Wọ́n pè é sí Nigerian Bar ní ọdún 1978.[6][7]
|url-status=
<ref>
self