Ìdìbò gbogbogbòò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọdún 2007 láti yan olórí orílẹ̀ ede ati ọmọ ilé ìgbìmò asòfin àpapọ̀ wáyé ni ọjọ́ kọkànlélógun , oṣù kerin, ọdún 2007.[1]
Àgbétẹ́lẹ̀
Ní ọjọ́ kẹrindínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2006, àwọn ilé ìgbìmò asòfin dibò láti ṣe àtúnṣe ìwé òfin pé kí olórí orílẹ̀ èdè máa ṣàkóso ju ìgbà méjì lọ lórí àlèéfa. [2] Ààrẹ Olusegun Obasanjo ko lépa igba keta .Ní àfikún kò rí àtìlẹyìn  Igbákejì rẹ̀ Atiku Abubakar. Ìpolongo àwọn olùdíje fún Olórí orílẹ̀ èdè wáyé ni ìpárí oṣù Kejìlá, ọdún 2006 àti ípàṣẹ fún àwọn ìbọn ìkọlù tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) níye láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ológun láti ṣètò ìdìbò létòletò lakoko idibo. [3] Umaru Yar'Adua jẹ́ olùdíje fún ẹgbẹ́ òṣèlú àlábúradà Peoples Democratic Party(PDP) àti Muhammadu Buhari tí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ alátakò All Nigeria Peoples Party (ANPP) . [4] Atiku Abubakar, Igbákejì Ààrẹ tó wà nípò kéde ní ọjọ́ karùn-ún dínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 2006 pé ohun yóò díje [5] Ó sì padà jáde gẹ́gẹ́ bíi olùdíje fun ipò Ààrẹ ti ẹgbẹ́ Action Congress ni oṣù Kejìlá. [6]
Àwọn Olùdíje
Àjọ elétò ìdìbò ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (INEC) sọ pé Abubakar kò lẹ̀tọ́ láti díje látàrí ẹ̀sùn jìbìtì tí wọ́n fi kàn án. Ilé ẹjọ́ gíga ti pàṣẹ pé ìgbìmọ̀ náà kò lè yọ olùdíje kúrò, ṣùgbọ́n Ìgbìmọ̀ Àjọ Eleto Ìdìbò (INEC) sọ pé òfin ti dá irúfẹ́ olùdíje bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kọ́ láti díje tí wọ́n bá ti fi ẹ̀sùn kàn[7][8]
Àjọ elétò ìdìbò ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (INEC) sọ pé Abubakar kò lẹ̀tọ́ láti díje látàrí ẹ̀sùn jìbìtì tí wọ́n fi kàn án. Ilé ẹjọ́ gíga ti pàṣẹ pé ìgbìmọ̀ náà kò lè yọ olùdíje kúrò, ṣùgbọ́n Ìgbìmọ̀ Àjọ Eleto Ìdìbò (INEC) sọ pé òfin ti dá irúfẹ́ olùdíje bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kọ́ láti díje tí wọ́n bá ti fi ẹ̀sùn kàn. Ilé ẹjọ́ gíga míràn, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, pàṣẹ ní ìwòyí fún INEC pé Ó ni àṣẹ láti yọ olùdíje. Abubakar gbìdánwò láti rí ìwé ìdìbò nípasẹ̀ ìpèníjà ilé ẹjọ́. Níbi ẹjọ́ tó wà ní ilé ẹjọ́ Apex, ilé ẹjọ́ náà pàṣẹ pé INEC kò ni àṣẹ láti yọ olùdíje fun ìdìbò, láti máa wá fún Abubakar láti díje. Ilé ẹjọ́ ti ó ga jù lọ lorílẹ̀ èdè jerisi àṣẹ yii àti ṣíṣe àtúnṣe ìdíje Abubakar. [9]
Àwọn ìtọ́kasí