Ẹdẹ jẹ́ ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, gúúsù ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ó wà ní ẹ̀ba Ọ̀sun ní ààyè kan lórí ojú-ìrìn láti Eko, 180 kilomita (110 mi) gúúsù ìwọ̀-oòrùn, àti ní ìkóríta àwọn ọ̀na láti Oshogbo, Ogbomosho, àti Ile-Ife[2]. Àwọn àgbègbè ìjọba ìbílẹ̀ méjì ni Ẹdẹ ní Ẹdẹ South àti Ẹdẹ North. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga mẹ́ta ni ó wà ní Ẹdẹ, èyítí ó jẹ́ kí ìlú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ó dàgbà jù ni gúúsù ìwọ̀-oòrùn pẹ̀lú ìwọ̀n ìmọ̀wé tí ń pọ̀ si. Federal Polytechnic Ẹdẹ, Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Adeleke, àti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Olurapada wà láàrin àwọn ilé-iṣẹ́ náà.
Tún wo
Àwọn ìtọ́kasí