Ìtàn nípa eré onítàn èdè Yorùbá

Eré onítàn ni eré tí a mọ̀n-ọ́n-mọ̀n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní ònà tí yóò fi dá àwọn òǹkàwé lárayá. Ó jẹ́ eré tí òǹkọ̀wé máa fi ń sọ̀ ìtàn. Àwọn òǹkọ̀wé eré onítàn máa n fi eré wọ́n sòrọ̀ nípa onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó n ṣẹlẹ̀ láwùjọ ni. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lè jẹ́ èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, èyí tí ó n ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí èyí tí òǹkọ̀wé wòye pé ó lè wáyé ní ọjọ́ iwájú.

Ìdàgbàsókè eré onítàn àpìlẹ̀kọ èdè Yorùbá

Àwọn oníwèé ìròyìn kò gbẹ́yìn nínú ìdàgbàsókè eré onítàn Yorùbá kíkọ sílẹ̀. Ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí "Elétí Ọfẹ" ni ó gbé eré onítàn kan jáde ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹ̀ta, ọdún 1923. Àkọlé mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wón sì fún eré onítàn náà. Àkọlé àkọ́kọ́ ni "Rẹ́rìn ín Díẹ̀", ní ìgbà tí àkọlé kejì n jẹ́ "Pa mí n kú obìnrin". Àkọlé kẹta tí wọ́n fún eré onítàn náà ni "Ẹní máa kú pàdé ẹní máa pá á". Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Akíntàn tí ó jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn Elétí Ọfẹ n gbé eré onítàn náà jáde nínú ìwé ìròyìn rẹ̀. Eré onítàn yìí wá sí ìdánudúró ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹrin, ọdún 1923. (Ògúnṣínà 1982).

Orísi orúkọ mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ tí Akíntàn fún eré onítàn yìí ló mú Ògúnṣínà (1980) sọ pé ìgbìyànjú tàbí àbámọdá lásán ni kíkọ tí Akíntàn kọ eré onítàn náà jẹ́. Àhunpọ̀ eré onítàn tí Akíntàn gbé jáde yìí kò gùn rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì lọjú pọ. Iṣẹ́ tí Akíntàn fé rán àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún, kò mú ọ̀rọ̀ ìfìwàwẹ̀dá ní ọ̀kúnkúndùn. Gẹ́gẹ́ bí Ògúnṣínà (1982) ṣe sọ nìlùú Èkó ni ibùdó ìtàn eré onítàn tí Akíntàn kọ. Nínú èrò Ògúnṣínà eré onítàn náà kẹ́sẹjárí nípa ìlò èdè torí pé nínú ìpèdè òǹkọ̀tàn àwàdà àti ìpanilẹ́rìn-ín hànde.

A kò le pe eré onítàn tí Akíntàn gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Eletí Ofẹ tí ó sì fún ní orúkọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní eré onítàn àkọ́kọ́ torí pé kò sí ìdánilójú kankan pé Akíntàn sọ eré onítàn náà di odidi ìwé eré onítàn.

Lẹ́yìn akitiyan E. A. Akíntàn ní ọdún 1923, kò sí àkọsílẹ̀ eré onítàn kankan títí di ọdún 1958. Ní ọdún 1958 àwọn ìwé eré onítàn méjì ni ó jáde. Èkínní ni "Pàsán Ṣìnà" tí Adébòye Babalọlá kọ àti "Agbàlọ́wọ́ Mérìí Baálẹ̀ Jòntolo" tí Ọdúnjọ kọ. Àwọn eré onítàn méjèèjì yìí ni a le tọ́ka sí pé wọ́n jẹ́ eré onítàn àkọ́kọ́. Lẹ́yìn tí àwọn eré onítàn méjèèjì yìí ti jáde ní ọdún 1958 a kò tún gbúròó eré onítàn àpilẹ̀kọ kankan mọ́ títí di ọdún 1964 tí eré "Ká sòótọ̀ ká kú" jáde láti owó Ọlánípẹ̀kun Ẹ̀san.

Láti ọdún 1965 ni àwọn eré onítàn ọ̀kan-ò-jọ̀kan ti bẹ̀rẹ̀ síní jáde lára wọn ni Faleti (1965) "Wọ́n rò pé wèrè ni" Ọlabimtan (1966) "Olúwa ló mọ ẹjọ́ dá" àti "Ẹ̀san" (1968) Òrékelẹ́wà. Ọdún 1970 ni akitiyan kíkọ eré onítàn Yorùbá, ní báyìí ogunlọ́gọ̀ ni àwọn ìwé eré onítàn Yorùbá tí ó ti wà ní ìta, tí àwọn òǹkọ̀wé eré onítàn Yorùbá ń pọ̀ si lojoójúmọ́

Àwọn ìtọ́kasí

Strategi Solo vs Squad di Free Fire: Cara Menang Mudah!