Ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìlú Ilé-Ifẹ̀
Ṣaájú, ó yẹ ki a là á wí pé ohunkóhun tí a bá fi ẹnu bà lábẹ́ àkòrí yìí gbọdọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn ìwáṣẹ̀. Ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ àwọn ìtàn tó ti pẹ́ púpọ̀, tó sì ń sàlàyé ọ̀pọ̀lọpò ohun tí kò yé ẹ̀dá. Bascom nínú Finnegan (1970:361) ṣe àlàyé nípa ìtàn ìwáṣẹ̀ pe: Myths are prose narratives, which in the society in which they are told are considered to be truthful accounts of what happened in the remote past
(Ìtàn ìwáṣẹ ni àwọn ìtàn àròsọ tí àwọn ènìyàn àwùjọ ní ìgbàgbọ́ pé ó jẹ́ ìtàn òdodo nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́)
kò sí ẹ̀dá alààyè tàbí ibùgbé tí ìtàn ìwáṣẹ̀ kì í dá lé, a sì gbọ́dọ̀ gbà á gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ṣe sọ ọ́ ni nítorí kò sí ẹni tí o lè jẹ́rì í sí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojú òun. Finnegan (1970:362) fi ìdí èyí múlẹ̀, ó ní
… they are accepted on faith, they are taught to be believed; and they can be cited as authority in answer to ignorance, doubt, or disbelief. Myths are the embodiment of dogma: they are usually sacred and they are often associated with theology and ritual. Their main characters are animals, deities, or culture heroes whose actions are set in an earlier world, when the earth was different from what it is today, or in another world such as the sky or underworld
(… A gbà wọ́n pẹ̀lú ìgbàgbo, wọ́n jẹ́ ẹ̀kọ́ tó wà láti gbàgbọ́; a lè fi wọ́n ṣe ẹ̀rí àìmọ̀kan, iyèméjì tàbí àìgbàgbọ́. Ìtàn ìwáṣẹ̀ kún fún gbígba ohun kan gbọ́ láìwádìí, ọ̀wọ̀ wà fún wọn, wọ́n ṣáábà máa ń jẹ́ ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti ọ̀nà tí a ń gbà ṣe ẹ̀sìn. Àwọn ẹ̀dá pàtàkì inú wọn ni ẹranko, òrìṣà àti àwọn akọni nínú àṣà tí wọ́n ti kópa tó jọjú ní ayé àtijọ́ tàbí ayé mìíràn gẹ́gẹ́ bí ojú ọ̀run tàbí ìsàlẹ̀ ilẹ̀).
Àlàyé rẹ̀ yìí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀, kì í ṣe ohun à á yọ àdá bẹ́; òdú sì ni, kì í ṣe àìmọ̀ fun oloko. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú Ilẹ̀ Yorùbá ni wọn gbà pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti lọ, èyí kò sì jẹ́ kí ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀ ṣe àjòjì sí wọn.
Oríṣìíríṣìí ìtàn ìwàṣẹ̀ ló wà tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá Ilé-Ifẹ̀. Ìtàn ti a kà nínú ìwé tí ó sì tún ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí a gbà láti ẹnu àwọn abẹ́nà ìmọ̀ wa kò ju ìtàn méjì péré tí í ṣe ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ àti ìtàn Mẹ́kà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn ìtàn méjì náà ni wọ́n gbajúmọ̀ jù lọ. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtàn wọ̀nyí, a rí abala tí ó fará pẹ́ òtítọ́, a sì rí èyí tí kò fi gbogbo ara jẹ́ òtítọ́.
Nínú ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ ni a ti gbọ́ pé láti ìsálú ọ̀run ni Olódùmarè ti rán Odùduwà wá tẹ Ilé ayé dó. Kí Olódùmarè tó ran Odùduwà, ó ti kọ́kọ́ rán Ọbàtálá, ẹni tí àwọn Ifẹ̀ máa ń kì pe:
Ọbàtálá, obàtáàsà
Ọba takun takun lóde ìrànje.
Anihun ńlá mọ́ jugbè é.
Irin kọ́tọ́kọ́tọ́ kán an fi bọ̀wú
Afúruru bí ọyẹ́.
Ẹlẹ́jẹ ọ́ ọ́ fun ni í jẹ́.
A gbà gìrì dánù lọ́wọ́ òṣìkà.
Afúnni mọ́ tọwó ẹni.
Aránmọ lóko tín-in tín-in.
Aṣáran méegun.
Abéwúrẹ́ rojọ́ ìbẹ́rí.
Olódùmarè fún ọbàtálá ní adìyẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún àti erùpẹ̀ pé kí ó lọ fi tẹ Ilé ayé dó. Èèwọ́ Ọbàtálá ni pe kò rú ẹbọ kí ó tó máa bọ̀. Ó pàdé adẹ́mu, Èṣù si jẹ́ kí ó mu ẹmu yó. Ẹmu tó mu yìí mú ki ó sùn lójú ọ̀nà, kò le è lọ mọ́. Nigbà tí Olódùmarè retí rẹ̀ títí tí kò rí i, ó rán Odù tó dá ìwà tí í ṣe Odùduwà. Orìṣà atẹ̀wọ̀nrọ̀ ni Odùduwà nítorí pé ẹ̀wọ̀n ni ó fi rọ̀ wá sí ilé ayé. Abímbọ́lá (1969:26) ṣe ìtọ́kasí èyí nínú Ọ̀yẹ̀kú méjì.
Títí lorí ogbó.
Bììrìpé bììrìpé omi ọkọ̀ ọ́ dà
Dídà lomi ọkọ̀ ọ́ dà,
Omi ọkọ kì í yì,
A díá fún Oòduà atẹ̀wọ̀nrọ̀
Wọ́n ní bó rúbọ
Lọ́dún yìí ní ó goróyè baba ẹ̀
Bí ò rúbọ
Lọ́dún yìí ní ó goróyè baba ẹ
Odùduwà yìí kan náà ni ọlọ́fin Àdìmúlà, onile(ẹni tí ó ni Ilẹ̀).
Odùduwà yìí ló gba iṣẹ́ náà ṣe lọ́wọ́ Ọ̣bàtálà. A gbọ́ pé ibi tí
Odùduwà àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ rọ̀ sí ni wọ́n ń pè ní òkè Ọ̀ràmfẹ̀ lónìí. Níbẹ̀ ni Odùduwà ti rí omi tí ó tẹ́jú lọ, ó sọ adìye yìí sí orí omi yìí, adìyẹ yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí tan yanrìn náà títí. A sì sọ ọ́ di ilẹ̀ Ifẹ̀. Èyí ni pé ilẹ̀ ẹ́ fẹ̀. Ibi tí ó tan yanrìn náà de ni òkun, ibi tí Odùduwà wá tẹ̀dó sí ni Ilé-Ifẹ̀. ìdí nìyí tí àwọn Ifẹ̀ ṣe màa ń ki Odùduwà ni:
Odùduwà onílẹ̀ gbẹ̀gi
Àdìmú kùtù wẹ̀
Ọlọ́fin ìsẹ̀dáyè
Òdùduwà atẹ̀wọ̀nrọ̀ sífẹ̀
Ìtàn àtẹnudẹ́nu ni ìtàn yìí gẹ́gẹ́ bí Fásọgbọ́n (1985:1) ṣe sọ pe;
According to the oral traditional history of Ilé-Ifẹ̀, Odùduwà was instructed to throw with a fowl of five toes to spread the grains of sand with a view to reclain the land from the water
(Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ìlú Ilé-Ifẹ̀, Odùduwà gba àṣẹ láti da iyẹ̀pẹ̀ sí orí omi pẹ̀lú adìyẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún kí omi náà le di ilẹ̀)
Ní èrò tiwa, ìtàn yìí fara pẹ́ òtítọ́ ní àwọn ọ̀nà kan, ó sì jìnnà sí òtítọ́ ní àwọn ọna mìíràn. Ìdí òtítọ́ rẹ̀ ni pé èdè Ifẹ̀ “ilẹ̀ ẹ́ fẹ̀” hàn nínú orúkọ tí wọn sọ ìlú náà tí í ṣe ilẹ̀ Ifẹ̀ tí ó di Ilé-Ifẹ̀. Bákan náà, èdè wọn hàn nínú orúkọ oyè ọba wọn “Ọọ̀ni”. Àpètán Ọọ̀ni ni “ọni kọ́ ni ilẹ̀”. “Ẹni” ni Ifẹ̀ ń pè ni “Ọni”. Nítorí náà, Ẹni tí ó ni ilẹ̀ wá di Ọọ̀ni ilẹ.
Yàtọ̀ fún èyí, wọn a máa ki ifẹ̀ ni:
Àbú onífẹ̀ Ọọ̀ni
Àbú onífẹ̀ Akẹ̀yò
Àbú onífẹ̀ ọmọ Sòókò
Ìwádìí fi hàn pé “Àbú” túmọ̀ sí ìpìlẹ̀ tàbí ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Ìdí nìyí tí
Ifẹ̀ ṣe máa ń pe ọmọ tuntun jòjòló ní Àbú róbótó. Èyí ni pé ọmọ tí
ó ṣẹṣẹ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tirẹ̀ lóde ayé.
Ẹ̀wẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọọ́lẹ̀ lo fi ìdí rẹ múlẹ̀ pé Ilé-Ifẹ̀ ni ayé ti bẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ Johnson (1921:15) ni:
All the various tribes of the Yoruba nation trace their Origin from Oduduwa and the city of Ilé-Ifẹ̀. In fact Ile-Ife is fabled as the spot where God created man white and black and from whence they dispersed all over the earth .
(Gbogbo ẹ̀yà Yorùbá lo tọsẹ̀ orírun wọn sí Odùduwà, a tilẹ̀ gbọ́ ọ nínú ìtàn pé Ile-Ifẹ̀ ni Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá ènìyàn, yálà funfun tàbí dúdú tí wọ́n sì ti ibẹ̀ fọ́n káàkiri ilé ayé).
Bákan náà ni Adeoye (1979:28) se àlàyé pé Ilé-Ifẹ̀ ti fi ìgbà kan jẹ́ Olú ìlú fún àwọn ọmọ aládé mẹ́rìndínlógún kó tó di pé wọ́n pínyà.
Lọ́jọ́ tí wọn yóò sì jáde ní ìta ìjerò ní ibi tí ilé-ifẹ̀ ti wà ní òwúrọ̀ ọjọ́ (ibẹ̀ wà láàrin Ifẹ̀wàrà àti ilé-ifẹ̀ lónìí) lábẹ́ Igi ọdán àti pèrègún, ìta ìjerò yìí ni àwọn ọmọ aládé mẹ́rindínlógún yìí ti pínyà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe a rí àwọn ẹ̀rí bì í mélòó kan tí a fi lérò pé òtítọ́ ni ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ yìí, síbẹ̀ a kò lè fi gbogbo ara kà á sí òtítọ́ nítorí àwọn ìbéèrè kan wà tí a kò lè rí ìdáhùn fún bí a bá fi ojú ìmọ́ sáyéǹsí wò ó. Àwọn ìbéèrè náà ni pé; Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí ènìyàn fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ wá si ayé? Ǹjẹ́ a lè da iyẹ̀pẹ̀ sí inú omi kí ó má lọ si ìsàlẹ̀ odò, kí a má ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ pé adìyẹ̀? Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ ṣe é ṣe kí adìyẹ kan ṣoṣo tan ilẹ̀ dé gbogbo ayé? Ǹjẹ́ ìwọ̀nba iyẹ̀pẹ̀ díẹ̀ lè tó láti kárí gbogbo ayé? Níwọ̀n ìgbà tí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ rárá, a jẹ́ pé ìtàn ìwáṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rìírí tí a kàn ní láti gbà gbọ́ ni. Ó jìnà sí òtítọ́ púpọ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ni wọ́n sọ nípa itan kejì tí í ṣe ìtàn Mẹ́kà pé láti ìlú Mẹ́kà ni Odùduwà ti wá tẹ̀dó sí Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn onímọ̀ náà ni Johnson (1921:384), Owólabí (awy) (1986:2-8). Ní ìlú Mẹ́kà, Odùduwà yapa sí ẹ̀sìn abínibí rẹ̀ tí í ṣe ẹ̀sìn Lámúrúdu baba rẹ̀. Ìyapa yìí mú kí ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ láàrin Odùduwà àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Bùràímọ̀, ọmọ Odùduwà pàápàá lòdì sí Odùduwà baba rẹ̀ nítorí pé ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ní ṣe. Inú bí Odùduwà, ó sì pàṣẹ̀ pé kí wọ́n sun ọmọ rẹ̀ náà ni ààye. Inú bí awọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí yòókù, wọn gbógun ti Odùduwà. Odùduwà sá àsàlà kúrò ní Mẹ́kà, ó sì tẹ́dò sí Ilé-Ifẹ̀. Ó bá Àgbọnmìrègún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sẹ̀tílù. Àgbọnmìrègún yìí ló dá ẹ̀sìn ifá silẹ. Ìtàn náà tẹ síwájú láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ọmọ Yorùbá yòókù ti lọ. Ìtàn yìí fẹ́ dojúrú díẹ̀ nítorí oríṣìíríṣìí ìtàn ni a ń gbọ nípa ìran Yorùbá. Àwọn kan sọ pé Ọ̀kànbí nìkan ni ọmọ Odùduwà tí Ọ̀kànbí sì wá bí àwọn ọmọ méje tí wọ́n jẹ́ ọba Aládé káàkiri ibi tí a lè tọpasẹ̀ àwọn Yorùbá dé lónìí. Àwọn mìíràn gbà pé àwọn méje wọ̀nyí kì í ṣe ọmọ-ọmọ Odùduwà, pé ọmọ Odùduwà gan-an ni wọ́n àti pé kì í ṣe ìyàwó kan ṣoṣo ni Odùduwà ni. Èrò yìí ni Mákindé (1970:8) fi hàn nígbà tí ó sọ pé:
Among the wives of Odùduwà were Atiba, Omitoto and Olókun. He had children by many of them. The children set up Obaship and Chieftaincy institutions in the various parts of Yorùbá land
(Lára àwọn ìyàwó Odùduwà ni Àtìbà, Omìtótó àti Olókun. Púpọ̀ nínú wọn ni ó bí ọmọ fún un. Àwọn ọmọ náà sì gbé ìjọba àti ètò ìṣèlú kalẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá).
Ìtàn tí ó gbà pé Odùduwà ni ó bí àwọn ọmọ méje tó tẹ ilẹ̀ Yorùbá dó sọ pé Olówu ni àkọ́bí Odùduwà. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn, obìnrin ni Olówu. Olówu yìí ni ó gbé àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin wá kí Odùduwà. Odùduwà gbé ọmọ náà lé ẹsẹ̀. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń fa mọ́ adé orí bàbá ìyá rẹ̀. Odùduwà ṣí adé, ó sì fi lé ọmọ náà lórí, ọmọ náà sì gbàgbé sùn lọ tòun tadé lórí. Èyí mú kí Odùduwà yọ̀ǹda adé fún ọmọ náà nígbà tí ó jí. Bóyá ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń ki àwọn Òwu ní
Asunkún gbadé ọmọ ato
Ọ̀ṣẹmìnì gbokùn ọmọ Ìgbómìnà
Ajíkágboro, Arìnkágboro
Ò jí kùtù fomi ìgboro bọ́jú
Àwọn ọmọ Odùduwà tó kù lẹ́yìn Olówu ni Aláketu ti Kétu, Ọba Ìbíní,
Ọ̀ràngún ilé Ìlá, Onísábé ti ilẹ̀ Sábẹ́, Olúpópó tí í ṣe ọba Pópó àti Ọ̀rányàn. Ìtàn tó tọ́ka sí Ọ̀kànbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ kan ṣoṣo tí Odùduwà bí náà gbà pé Ọ̀ràńyàn ni àbígbẹ̀yìn ọ̀kànbí. Nígbà tí bàbá wọn kú. Ọ̀rányàn kò sí nílé, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì pín gbogbo dúkìá bábá wọn mọ́ ọwọ́, ilẹ̀ nìkan ni wọ́n fún un. Ó gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún un, ó sì sọ ọ́ di dandan fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ láti máa san ìsákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. Èyí mú kí ó di olówó, alágbára àti olókìkí láàrin àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Johnson (1921:8) jẹ́rì í sí èyí pé;
Ọ̀rányàn was the youngest of Odùduwà’s grandchildren, but eventually, he became the richest and most renowned of them all.
(Ọ̀rányàn ni abigbẹyin nínú àwọn ọmọ-ọmọ Odùduwà, ní
Ìkẹyìn, ọrọ̀ àti òkìkí rẹ̀ tayọ tí gbogbo wọn)
A gbọ́ pé ń ṣe ni Ọ̀ràńyàn ń lọ láti ìlú kan sí ibòmíràn tí ó sì ń tẹ ìlú dó bí ó ti ń lọ káàkiri. Lára àwọn ìlú náà ni Ọ̀yọ́-Ilé, Ahoro Òkò, Ìkòyí, Ilé Igbọn, Ìrẹsà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A gbọ́ ọ bákan náà pé àwọn ọmọ Odùduwà ju méje lọ. Àwọn òpìtàn mìíràn ń fi Aláké Ẹ̀gbá àti Obòkun ti Ìjẹ̀ṣà mọ́ wọn. Oyèbámijí (awy) (1990:4) ni
Òpìtàn kan náà, Àlùfáà Johnson tún fi yé ni pé Aláké àti Ọwá jẹ́ ọmọ Odùduwà tí wọ́n sì lọ tẹ̀dó sí Aké ní orílẹ̀-Aké àti ní ilẹ̀ Ìjẹ̀sà níbi tí wọ́n wà di òní yìí
Owólabí (awy) (1986:8) sọ pé bí ìran Yorùbá ṣe wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjírìà ni wọ́n wà káàkiri àgbáńlá ayé bí i ilẹ̀ Sàró, Gánà, Tógò, Bìní, ilẹ̀ Àmẹ́ríkà, Bùràsíìlì, Jàmáíkà àti ogunlọ́gọ̀ erékùsù tí ó wà káàkiri òkun Àtìláńtììkì. Lórí bí àwọn ọmọ Yorùbá ṣe ta gbòǹgbò káàkiri àgbáyé yìí náà ni Akínyẹmí (1991:586) sọ̀rọ̀ lé nígbà tí ó ní:
Ifẹ̀ ni wọ́n ń pe Yorùbá orílẹ̀ èdè Tógò. Àwọn Yorùbá tó sì wà ní orílẹ̀ èdè Benin pín sí méjì ‘ìdásà’ àti ‘Manígì’. Kì í ṣe orílẹ̀ èdè mẹ́ta yìí nikan ni Yorùbá wà. Àwọn onímọ̀ bíi Abímbọ́lá, Turner àti Watkins ti ṣe áláyè pé àwọn ẹni tí wọ́n kó lọ orílẹ̀ èdè ‘Cuba’, ‘Brazil’ àti America’, wà níbẹ̀ lónìí tí wọn ń gbé èdè àti àsà Yorùbá lárugẹ. Àwọn Yorùbá tó wà ni ‘cuba’ ni wọ́n ń pé ní ‘Lucumi’. Àwọn tó wà ni ‘Brazil’ ni wọ́n ń pè ni ‘Nàgó’.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, abala kan ìtàn tí ó sọ pé Odùduwà wa láti Mẹ́kà fara pẹ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni apá kan rẹ̀ jìnà sí òtítọ́. A lè ka ìtàn Mẹ́kà yìí sí òtítọ́ nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣìíríṣìí àkọọ́lè ló wà tó tọ́ka sí Odùduwà àti Ilé-Ifẹ gẹ́gẹ́ bí orírun ọmọ Yorùbá tí oríṣìíríṣìí àkọọ́lè sì wà pẹ̀lú pé mẹ́kà ni Odùduwà ti wá sí ifẹ̀, Ìtàn Mẹ́kà jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ju ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ lọ tí a ba fojú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn wò ó.
Tí a bá fi ojú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ìbára-ẹni gbépọ̀ wo ìtàn Mẹ́kà yìí, a kò le kà á sí òtítọ́ rárá. Ìdí ni pé ìrísí àwọn ènìyàn Ifẹ̀ àti ìran Yorùbá lápapọ̀ yàtọ̀ gédégédé si ti awọn ara Mẹ́kà bẹ́ẹ̀ sì ni àṣà àti ìṣe wọn kò bára mu.
Àkíyèsí mìíràn tí a ṣe ni pé ìtàn yìí sọ pé Odùduwà bá Àgbọnmìrègún ni Ilé-Ifẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Odùduwà bá Àgbọnmìrègún ní Ile-Ifẹ̀, á jẹ́ pé Ilé -Ifẹ̀ ti wà kí Odùduwà tó dé.
Nínú ìtàn mìíràn, èyí tó fara jọ ìtàn inú Bíbélì, a gbọ́ pé nígbà ti ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀, àgbàrá òjò gbá gbogbo àwọn tó wà láyé nígbà náà lọ, Odùduwà wà lára àwọn tó yè, ìjọba tuntun sì bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ àkóso Odùduwà (Fábùnmi 1969:4) jẹ́rìí sí èyí pé:
…Odùduwà came neither from the East nor from the West but that he was one of the people who lived before the deluge, and that, after the deluge, he together with his followers and their families, descended unto dry land by means of chain-ropes from their life-boat which anchored on Oke-Ora.
(Odùduwà kò wá láti ìlà Oòrun tàbí ìwọ̀ oòrùn, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà láyé kí ìkún omi tó dé, àti pé lẹ́yìn ìkún omi, òun pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ àti àwọn ẹbí rẹ̀ fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ ìyè wọn, èyí tí ó gúnlẹ̀ sí Òkè-Ọ̀ra).
Èyí pàápàá tún fi òkodoro ọ̀rọ̀ náà hàn pé wọn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ilé ayé tàbí tẹ ìlú kan dó, àsìkò ìjọba kan sí èkejì ló ń ṣẹlẹ̀.
Ní ọ̀nà mìíràn, a kò tilẹ̀ gbọ́ nínú ìtàn àwọn Áráàbù pé Odùduwà fi ìgbà kan wà ní Mẹ́kà bẹ́ẹ̀ ni ìṣ̣ẹ̀lẹ̀ yìí ṣe pàtàkì ju pé kí òpìtàn ilẹ̀ Áráábù kankan má mẹ́nu bà á lọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtakora díẹ̀díẹ̀ wà nínú ìtàn méjèèjì òkè yìí, síbẹ̀ ìtàn méjèèjì ló tọ́ka sí Odùduwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó tẹ Ilé-Ifẹ̀ dó.