Ìpínlẹ̀ Bauchi(Fula: Leydi Bauchi 𞤤𞤫𞤴𞤣𞤭 𞤦𞤢𞤵𞤷𞥅𞤭) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní agbègbè àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kano àti Jigawa si àríwá, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Taraba àti Plateau sí gúúsù, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Gombe àti Yobe sí ìlà-oòrùn, àti pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kaduna sí ìwọ̀-oòrùn. Ó mu orúkọ rẹ̀ látara ìlú-onítàn Bauchi, tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí olú-ìlú rẹ̀. Wọ́n dá ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún 1976 nígbàtí Ìpínlẹ̀ àríwá-ìlà-oòrùntẹ́lẹ̀rí fọ́. O pẹ̀lú àwọn ojúlówó agbègbè tí ó kún Ìpínlẹ̀ Gombe, tí ó di Ìpínlẹ̀ tí ó dàyàtọ ní ọdún 1996.
Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Bauchi jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kéje ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́fà-àbọ̀-lé-ní-ẹgbẹ̀rúnlọ́nà-ọgbọ̀n gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.
Ohun tí a wá mọ̀ sí ìpínlẹ̀ Bauchi ti ní olùgbé láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ọ̀wọ́ ẹ̀yà, pẹ̀lú Bolewa, Butawa, àti Warji sí àáríngbùngbùn agbègbè; àwọn Fulani, Kanuri, àti Karai-Karai ní àríwá; àwọn fulani àti Gerawa nínú àyíká ìlú Bauchi; àwọn Zaar (Sayawa) ní gúúsù; àwon Tangale ní gúúsù-ìlà-oòrùn; àti àwọn Jarawa ní gúúsù-ìwọ̀-oòrùn the southwest.
Àwọn Itokasi