Àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nínú èyí tí ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń tọ́ka sí àkókò tí ó ṣáájú kí àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n gbajúgbajà ní àwùjọ wa lákòókò yìí ó tó dé. Ayẹyẹ ọdún àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì [1][2] àti ayẹyẹ ọdún àwọn Mùsùlùmí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tàbí ọ̀nà tí ó jọjú sí àwọn ènìyàn ibẹ́.[3]
Àjọ tí ó ń rí sí ìdàgbàsókè ètò ìrìnàjò afẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Nigerian Tourism Development Corporation) ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti jẹ́ kí wọn ó mọ ìwúlò àti ipa pàtàkì tí àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ máa ń kó, tí ó sì le jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí wọn á fi máa rówó láti ara ètò irinajo afẹ́.[4] Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ tí ó ń bẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lé ní ọ̀tà-lé-márùn-ún lélọ́ọ̀ọ́dúnrún (365), gẹ́gẹ́ bí Mínísítà tí ó ń rí sí ètò ìròyìn àti àṣà, ọ̀gbẹ́ni Lai Mohammed ti sọ, àti pé ìjọba ń ṣa apá wọ́n làti mú kí ìdàgbàsókè ó bá àwọn àṣà wa láti jẹ́ kí àwọn àgbáyé ó mọ bí a ṣe ní àwọn onírúurú àṣà ìbílẹ̀. [5][6]
Ọdún Mbà Boli ní Mambilla ní Ìpínlẹ̀ Taraba ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n máa ń ṣe àjọ̀dún yìí ní ọdọọdún nínú oṣù kọkànlá káàkiri agbègbè Mambilla ní Ìpínlẹ̀ Plateau. Ọdún yìí wà fún ìkórè àgbàdo (kuum-ngwuoni) àti ìdúpẹ́ fún Ọlọ́run.
Christians jẹ́ ìdá àádọ́ta àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n ń gbé káàkiri gbogbo ìlú ṣùgbọ́n tí wọ́n pọ̀ sí ẹkùn gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[19]
Àwọn ọdún àwọn ọmọlẹ́yìn Kirisiti ni ọdún Kérésìmesì (Christmas) àti ọdún àjíǹde (Easter).[20][21] Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe ọdún yìí máa ń ṣe àkósínú àwọn ìlànà ẹ̀sìn ìṣàájú.[3]
Wọ́n máa ń ṣe ọdún Kérésìmesì ni gbogbo ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kejìlá gbogbo ọdún, láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù (Jesus Christ).[22]
It is a public holiday in Nigeria.[23][24]
Ní ilẹ̀ àwọn Igbo, sí àfikún ètò ìjọsìn àti ẹ̀bùn híhá, ọdún náà máa ń ṣe àfihàn Mmo ijó egúngún, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ á ti wọ aṣọ aláràǹbarà àti àwọ̀sójú. Ijó yìí máa ń tọ́ka sí ìgbà tí ẹ̀sìn kìrìsìtẹ́nì wọlé dé àti láti fi yẹ́ ẹ̀mí àwọn baba-ńlá wọn sí.[25]
Ní àwọn àgbègbè kan, wọ́n máa ń lo ìmọ̀ ọ̀pẹ láti fi kọ́ gbogbo inú ilé, èyí jẹ́ àmì fún àlàáfíà àti àmì ọdún Kérésìmesì. [26]
Wọ́n máa ń ṣe ọdún àjíǹde láti fi bí wọ́n ṣe kan [Jésù]] mọ́ àgbélébùú ní ọjọ́ Ẹtì àti bí ó ṣe jí dìde ní ọjọ́ Àìkú.
Ọjọ́ tí ó bá bọ́ sí máa ń jẹ́ ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[23]
Wọ́n sáábà máa ń ṣe ọdún Àjíǹde nínú oṣù kẹrin ọdún.[27]
Ayẹyẹ ọdún àjíǹde jẹ́ ọdún àjọyọ̀ àti alárinrin, tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú ijó jíjó àti ìlú lílù.[28] Àwẹ̀dá gbígbà máa ń ṣáájú àjọyọ̀ èyí tí a mọ̀ sí àwẹ̀ Lẹ́ǹtì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹlésìn yìí ni wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí, ṣùgbọ́n àwọn kan a máa ṣe é tọkàntọkàn.
Ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì àti Àjíǹde le jẹ́ ìgbà tí ó lọ́ jàì láàárín àwọn ẹlésìn kìrìsìtẹ́nì àti àwọn Mùsùlùmí ní àwọn agbègbè kan.
Ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì ti ọdún 2010, àwọn ènìyàn bíi méjìdínlógójì ni wọ́n rán lọ́run.
Àwọn oníjà ẹ̀sìn Boko Haram ni wọ́n di ẹ̀bi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà rù.[29]
Àwọn ìròyìn kan jábọ̀ ikú àwọn ènìyàn tó tó Ọgọ́rin. [30]
Ní ọdún 2011, ayẹyẹ Àjíǹde wáyé lẹ́yìn ètò ìdìbò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí Goodluck Jonathan ti jáwé olúborí. Onírúurú àwọn ilé-ìjọsìn àwọn ọmọlẹ́yìn Kirisiti ni wọ́n dáná sun ní ẹkùn Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n sì pa àwọn ẹlésìn kìrìsìtẹ́nì nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sẹ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò. [31][32]
Àjọ̀dún àwọn Mùsùlùmí
Bíi ìdá sí méjì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí, tí wọ́n ń gbé káàkiri àwọn ìletò tó ń bẹ nínú ìlú náà,pàápàá jùlọ ní ẹkùn Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìdá mọ́kàndínlógójì ni wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí, ìdá àádọ́ta jẹ́ kìrìsìtẹ́nì, tí ìdá tó kú ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn. [33]
Ayẹyẹ ọdún méjì ni àwọn Mùsùlùmí máa ń ṣe; ọdún ìtúnu àwẹ̀ àti ọdún iléyá. Tí àwọn àkókò méjèèjì yìí jẹ́ àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [34][23]
Onírúurú àwọn ẹ̀yà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n máa ń ṣe àwọn ọdún yìí bákan náà. [3]
Ayẹyẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ti ìtúnu àwẹ̀ jẹ́ àjọyọ̀ fún píparí àwẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń gbà láti ìgbà tí àlìfájàrí bá ti yọ títí tí Òòrùn yóò fi wọ̀.
Àkókò yìí jẹ́ ìgbà tí wọ́n máa ń fún àwọn aláìní àti ọmọ òrukàn ní nǹkan, tí wọ́n sì máa ń ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí àti ará. [35]
Ọdún iléyá jẹ́ ọdún tí wọ́n máa ń ṣe káàkiri àgbáyé, èyí tí ó sọ ìtàn bí Ànọ́bì Abraham (ʾIbrāhīm) ṣe fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo Íṣímáẹ́lì jọ́sìn fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi ìbọ̀wọ̀ àti ìgbàgbọ́ tí ó ní sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run padà bá a fi àgbò dìrọ̀ ẹ̀mí ọmọ rẹ̀. Àwọn Mùsùlùmí a máa pa àgbò, ewúrẹ́, àgùntàn, màálù, tàbí ràkúnmí fún ọdún iléyá tí wọ́n á sì pín àwọn ẹran yìí fún àwọn aláìní láwùjọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kejìlá kọ́jọ́dá àwọn Mùsùlùmí.[36][37]
Ayẹyẹ ọdún Durbar jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní àkókò ọdún ìtúnu àwẹ̀ àti ọdún iléyá.[38] ayẹyẹ Durbar ni wọ́n ti ṣe ní àìmọye ọdún ní àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọ́n wà ní Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí a mọ̀ wọ́n sí Daura Emirate, ó máa fún àwọn ọmọ ológun láàyè láti pidàn oríṣiríṣi. Ní àwọn ìgbà kan sẹ́yìn wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí nípa lílọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin yóò sì fi ẹṣin wọn pitu oríṣiríṣi.[4]
Modern Durbar festivals include prayers at the start of the day, followed by parades in town squares or in front of the local emir's palace. Horsemanship is still the main focus. Each group must gallop at full tilt past the Emir, then halt and salute him with raised swords.[39]
Durbar festivals are being developed as important tourist attractions.[40] Ní àsìkò àjàkâlẹ̀ ààrùn COVID-19 ní àwọn ìlú, àwọn Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pinu láti fi ètò náà rọ̀ sí ibìkan láti bọ̀wọ́ fún òfin àti ìlànà kíkó ara ẹni jọ, bí a ti mọ̀ pé ọdún yìí máa ń fa èrò káàkiri àgbáyé wá.[41][42][43][44]
Ayẹyẹ ọdún yìí jẹ́ ọdún àṣà àti ẹ̀sìn èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọdọọdún. Àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ọba Kòsọ́kọ́ ni wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí fún ìrántí bí ọba yìí ṣe tẹ̀dó sí Epe ní ọdún 1851.[45][46] Wọ́n mọ àwọn ará Ẹ̀pẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ékó (Lagos State) fún ọdún Káyó-Káyó, èyí tí ó túmọ̀ sí pé "kí á jẹun tí a fi máa yó." Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní kọ́jọ́dá àwọn Mùsùlùmí, èyí tí ó jẹ́ oṣù kan lẹ́yìn ọdún iléyá àwọn Mùsùlùmí.[47][48][49]
Ojúde Ọba jẹ́ ayẹyẹ ìsẹ̀m̀báyé, tí àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n ń bẹ ní Ijebu Ode, agbègbè kan ní Ìpínlẹ̀ Ògùn (Ogun State), ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa ń ṣe. Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọdọọdún ní ọjọ́ kẹta ọdún iléyá àwọn Mùsùlùmí, láti ṣe ìbọ̀wọ̀ fún Ọba Awujalẹ tí ìlú Ijebul. Ó jẹ́ ọdún tó lààmìlaaka tí ó sì gbajúmọ̀ ní ìlú Ìjẹ̀bú àti jnní gbogbo Ìpínlẹ̀ Ògùn (Ogun State) pátá.[50][51]
Ó jẹ́ ayẹyẹ ọlọ́jọ́ kan, níbi tí àwọn onírúurú ẹgbẹ́ àṣà ìbílẹ̀ tí a mọ̀ sí (regberegbe), àwọn ọmọ ìlú, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ nítòsí àti ibi tí ó jìnnà yóò ti wá ṣe eré ní ojúde ọba ní ọjọ́ kẹta ọdún àwọn Mùsùlùmí tí a mọ̀ sí ọdún iléyá.[52][53] Ọba Adétọ̀nà ni ó kó àwọn ẹlẹ́gbẹ́ àṣà padà wá ní sẹ́ńtúrì kejìdínlógún (18th century).[51]
↑OPEYEMI AGBAJE (27 April 2011). "Innocent blood at Easter". BusinessDay. Archived from the original on 28 September 2011. Retrieved 2011-04-27.Unknown parameter |url-status= ignored (help)
↑ 51.051.1Anifowose, Titilayo (2020-05-01). written at Lagos, Nigeria. "Cultural Heritage and Architecture: A Case of Ojude Oba in Ijebu Ode South-West, Nigeria". International Journal of Advances in Scientific Research and Engineering (University of Lagos Akoka Nigeria) 6 (5): 74–81. doi:10.31695/IJASRE.2020.33808.
↑"Ojude Oba Festival". Ogun State Government Official Website (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-08-02. Retrieved 2021-08-31.Unknown parameter |url-status= ignored (help)
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "ArgentEmbassy" defined in <references> is not used in prior text.