Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Central African Republic |
---|
Àrùn | COVID-19 |
---|
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
---|
Ibi | Central African Republic |
---|
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
---|
Index case | Bangui |
---|
Arrival date | 14 March 2020 (4 years, 8 months, 1 week and 6 days) |
---|
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 4,356 (as of 14 July)[1] |
---|
Active cases | 3,074 (as of 14 July) |
---|
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,229 (as of 14 July) |
---|
Iye àwọn aláìsí | 53 (as of 14 July) |
---|
Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè Central African Republic lóṣù kẹta ọdún 2020
Bí ó ṣe ìbẹ̀rẹ̀
Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[2][3]
Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[4][5] ṣùgbọ́n jíjàkálẹ̀ àrùn náà lágbára ju SARS lọ, pàápàá jù lọ iye àwọn ènìyàn tí àrùn náà ń pa lápapọ̀.[6][4]
Ẹ̀rọ amúnimí mẹ́ta péré ni ó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà.[7]
Jíjàkálẹ̀ àrùn náà láti ìgbà dé ìgbà
Oṣù kẹta ọdún 2020
Lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún 2020 ni wọ́n kọ́kọ́ kéde ẹni àkọ́kọ́ tí ó ní àrùn náà lórílẹ̀ èdè Central African Republic. Alárùn náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin ((74) ọmọ orílẹ̀-èdè Italy tó padà sí Central African Republic láti ìlú Milan.[8]
Ènìyàn mẹ́fà péré ni wọ́n kéde pé wọ́n ní àrùn náà lóṣù kẹta, kò sí ẹnì tí ara rẹ̀ yá tàbí kú nínú wọ́n.[9]
Oṣù kẹrin ọdún 2020
Ènìyàn tuntun mẹ́rìnlélógójì ni wọ́n kéde wọn pé wọ́n kó àrùn náà. Èyí wá jẹ́ kí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ní àrùn náà di àádọ́ta (50). Eni mẹ́wàá rí ìwòsàn, tí àwọn ogójì ṣì ní àìsàn náà títí di ìparí oṣù náà.[10]
Oṣù karùn-ún ọdún 2020
Lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù karùn-ún ni ẹni àkọ́kọ́ kú lórílẹ̀-èdè náà látàrí àrùn náà.[11]
Lóṣù karùn-ún, àpapọ̀ àwọn ènìyàn tuntun tí wọ́n ní àrùn náà jẹ́ 961, èyí tí ó mú kí iye àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ní àrùn náà ní Central African Republic jẹ́ ẹgbẹ̀rúnkanlémọ́kànlá (1011). Ènìyàn méjì péré ló kú, tí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n lu àlúyọ nínú àìsàn náà jẹ́ mẹ́tàlélógún (23).[12]
Oṣù kẹfà ọdún 2020
Lóṣù kẹfà ọdún 2020, iye àwọn ènìyàn tuntun tí wọ́n ní àrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Central African Republic jẹ́ 2734, èyí jẹ́ kí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ní àrùn náà níbẹ̀ jẹ́ 3745. Àpapọ̀ àwọn tí àìsàn náà pa jẹ́ mẹ́tàdíláàdọ́ta (47). Iye àwọn tí wọ́n rí ìwòsàn gbà jẹ́ 878,tí àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ṣì ní àrùn náà jẹ́ 2911 titi di ìparí oṣù náà.[13]
Àwọn Ìtọ́kasí