Yemọja jẹ́ òrìṣà inú omi gẹ́gẹ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn àbáláyé tàbí ìṣẹ̀ṣe Yorùbá.[1] Yorùbá ìgbàgbọ́ pé, Yemoja jẹ́ ìyá gbogbo àwọn òrìṣà pátápátá.[2] Ó tun jẹ́ ìyá gbogbo ènìyàn adáríhunrun. Òun ni òrìṣà omi tí ó lágbára jù lọ tí ó fi Odò Ògùn ṣe ibùgbé ní Nigeria, bẹ́ẹ̀ náà òun ló fi odò Cuba ṣe ibùgbé nínú ìgbàgbọ́ ẹṣin òrìṣà Brazil. Àwọn mìíràn gbàgbọ́ pé òun ni Our Lady of Regla ẹ̀sìn àwọn Afro-Cubandiaspora tàbí Màríà wúńdíá nínú ẹ̀sìn ìjọ Kátólíìkì, àṣà tí a gbàgbọ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ nígbà oko-owo ẹrú gba orí odò ilẹ̀-adúláwòAfrica. Yemọja jẹ́ òrìṣà abo tó lágbára tí ó sì máa ń tọ́jú, tí ó sì máa dá ààbò bo gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ nípa fúnfúnwọ́n ní ìrọrùn, tí ó sì máa ń pawọ́n mọ́ nínú èwù tàbí ìbànújẹ́ gbogbo. Wọ́n gbàgbọ́ pé ó máa ń sọ àgàn di ọlọ́mọ. Owó-ẹyọ ni àmìn ọlá àti ọrọ̀ rẹ̀. Kìí tètè bínú, ṣùgbọ́n bí ó bá bínú, ó lè ba nǹkan jẹ́ lọpọlọpọ bí omi òkun ṣe máa ń rú. Àwọn ìyá-òrìṣà Yemọja kan gbagbọ pé òun ló fi omi ọsà rẹ̀ fi ṣe iranlọwọ fún Ọ̀bàtálá nígbà tí ó ń dá ènìyàn láti ara amọ̀.
Àwọn mìíràn gbà pé Yemọja ni Màmíwọ̀tá, òrìṣà odò tí ó jẹ́ ìdajì ẹja àti ìdajì ènìyàn. Wọ́n gbà pé ó jẹ́ òrìṣà abo, òrìṣà òṣùpá láàárín àwọn ẹlẹ̀sìn rẹ̀ mìíràn ní ìlú ọba. Ó jẹ́ olùdáààbò bo àwọn obìnrin. Òun ni wọ́n gbà pé ó ń darí gbogbo ohunkóhun tí ó bá jẹ́mọ abo, wọ́n gbà pé abiyamọ ni, aláàbò, olùwòsàn àti olùfẹ́ràn àwọn ọmọdé. Wọn gbagbọ pé ìbínú rẹ̀ ni ó máa ń fa ẹ̀kún - omi tó lágbára. Bákan náà wọ́n gbagbọ pé láti ara rẹ̀ ni a ti dá ènìyàn àkọ́kọ́.