SÍNTÁÀSÌ YORÙBÁ
(1) Kí ni Sińtáàsì? Síńtáàsì ni èka kan gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa mú enu ba ohun ti a pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ní ìyín ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò so òrò ti ó mógbón lówó.
Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà,
(1) (a) Mo lo sí oko
(b) Sí lo oko mo
Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nip é ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu.
O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé.
(2) (a) Àwon ti ó lo kò pò
(b) Àwon ti wón lo kò pò
Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí.
Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so.
(2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b).
(3) (a) Olú gíga lo
(b) Olú lo
Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn.
3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni
a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye.
Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere:
(4) GB APOR APIS
Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5).
(5) GB APOR AF APIS
Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí:
(6) AF AS, IB, M, IBM
Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS.
(4) APOR: Èyí ni eni ti ó kópa nínú ohun ti òrò-ìse ń so. OR tàbí arópò-orúko (AR) ni ó máa ń jé olórí fún/APOR. Ohun tí a máa ń pè ní olórí fún àpólà kan ni òrò kan soso tí ó bá è dúró fún àpólà yen. Fún àpeere omo ni olórí fún (7a) àti (7b) àpólà orúko sì ni méjèèjì. Mo ni olórí fún àpólà orúko olùwà ní (7d), arópò-orúko sì ni mo yìí.
(7) (a) Omo pupa
(b) Omo
(d) Mo lo
A lè bá àpólà orúko ni ipò olùwà (èyí ni a fa ìlà sí ní ìdí ni (8a), ipò àbò (òun ni a fa ìlà sì ní ìdí ni (8b) àti ní i`po àbò fún atókùn nínú gbólóhùn (wo òrò tí a fa ìlà sí ní ìdi ní (8d)).
(8) (a) Aso pupa ti ya
(b) O ti ya aso pupa
(d) Ó rí Olú ni ilé
òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè tún APOR ko ni:
(9) APOR ---> OR APAJ
Àpólà àpèjúwe ni APAJ dúró fún. Láti fi hàn pé OR ni ó se pàtàkì jù nínú APOR, a lè ko òfin ìhun gbólóhùn wa báyìí.
(10) APOR ---> OR (APAJ)
Àmì yìí “( )” dúró fún pé ohun tí ó wà nínú rè kò pon dandan. Àkámó ni a ń pe àmì yìí. Níbi tí a kò bá ti lo àmì yìí, gbogbo ìsòrí òrò tí ó tèlé àmì ofà yen ni ó pon dandan nìyàn. A lè fi àwòrán-atóka igi fi èyí hàn báyìí. (11) nìkan ni a lé rì nínú (9);
Àwòrán-atóka igi (11) ní èka, ti (12) kò ní. Aróp-orúko náà lè dúró gégé bí APOR. Òfin ìhun gbólóhùn (13) fi èyí hàn.
(13) APOR --> AR
Nìgbàkúùgbà tí a bá tin i a rópò-orúko gégé bi APOR, arópò-orúko náà kì í ní èyán nítorí a kì í fi òrò mìíràn yán arópò-orúko ní èdè Yorùbá béè ni a kì í fi arópò-orúko Yorùbá yán òrò mìíràn. Àwòrán-atóka igi bíi ti (12) náà ni a ó lò fún òfin ìhun gbólóhùn (13). Ìyàtò tí ó kàn níbè kò ju pé dípò OR, a ó lo AR.
A lè so gbogbo òfin ìhun gbólóhùn APOR ti a ti ń ko láti òni (wo (9), (10) àti (13)) di eyo kan.
Àkámó onídodo ni a ń pe àmì yìí “ ” . Ohun tí ó ń fi hàn nip é a ó mú òkan nínú AR àti OR (APAJ). A ti so télè pé ohun tí kò pon dandan ni àmì yìí “( )” ń fi hàn.
(17) (a) Mo lo
(b) Olú lo
(d) Omo pupa lo
(e) Omo pupa tí ó ga lo
Òfin ìhun gbólóhùn tí ó gbé (17e) jáde ni (18) tí a lè rí ni (16)
(18) APOR ---> OR (APAJ GB)
Àfikún ni ohun tí a pè ní AFK nínú àwòrán yìí. Ohun tí ó dúró fún ni àwon òrò bíi tí (Omo ti ó lo), pé (Ó so pé ó lo) abbl tí a ń pè ní atíka gbólóhùn. Ohun tí tirayáńgù tí ó wà ní (19) dúró fún ni pé a kò fé fó ohun tí ó wà ní abé rè sí wéwé nítorí pé kò se pàtàkì fún ohun tí a ń so lówó. Sé e mò pé a tì lè fó GB sí APOR, AF àti APIS, a kò se èyí nítorí pé kò je wá lógún nínú ohun tí a ń so lówó. A lè so APOR mó APOR lábé APOR. Òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè fi èyí hàn ni (20); (21) sì ni àwòrán-atóka igi rè.
(20) APOR ---> AS APOR
Òrò-àso ni AS dúrú fún
5 APIS
Òrò-ìse (IS) ni olórí fún àpólà ìse (APIS). APIS ni a máà ni a máa ń pò ní kókó gbólóhùn nínú àwon ìwé tètèdé onígírámà nítorí pé ó ní òrò-ìse nínú. Òrò-ìse ni ó máa ń so ohun tí APOR se nínú gbólóhùn. Gégé bí olórí fún APIS, ó pon dandan kí òrò-ìse wà nínú gbólóhùn yálà pèlú àwon emèwà rè tàbí ní òun nìkan.
5i. ÌGBÀBÒ TÀBÍ ÀÌGBÀBÒ: Òfin ìhun gbólóhùn tí a fi máa ń tú APIS pale ni
(22) APIS ---> IS X
“X” jé bí àfikún fún òrò-ìse nínú APIS. Àfikún yìí lè dúró fún ìsòrí òrò kan tàbí àpólà. Ó ye kí á tètè se àlàyé síwájú sí i nípa ìgbàgbò tàbí àìgbàbò òrò-ìse. Òrò-ìse tí ó gbàbò ni òrò-ìse tí ó bá ní APOR gégé bí àfikún. Èyí tí kò bá ní APOR gégé bí àfikún ni òrò-ìse àìgbàbò. Ohun a ń so nip é òrò-ìse lè ní àfikún nínú gbólóhùn sine kí á pè é ní òrò-àìgbàbò. E wo (23) àti (24).
(23) Olú lo kíákíá
(24) Olú ra aso
Lóòótó (23) àti (24) ni ó ni àfikún fún òrò-ìse sùgbón sùgbón (24) nìkan ni lè so pé òrò-ise rè gba àbo. Ohun tí ó fá èyí ni wí pé APOR ni àfikún fún òrò-ìse (23) sùgbón àpólà àpónlé (APAP) ni àfikún fún òrò-ìse (24). A lè fi òfin gbé àlàyé àtúnpín sísòrí òrò-ìse tí a sese sàlàyé rè tán jáde báyìí.
(25) (a) ISagb + [---APOR]
(b) ISaigb + [ ---0]
A lè pa òfin méjèèjì yìí pò báyìí
(26) IS + [ ------------ (APOR)]
Yàtò si APOR àti APAP, IS tún lè rí àwon àfikún mìíràn. Àwon náà ni àpólà atókùn (APAT) àti gbólóhùn onípele (GB). A lè se àtúnpínsòrí IS pelú gbogbo won báyìí,
(27) (a) rí : IS; + [----- APOR] Mo rí Olú
(b) wá: IS; + [-----APAT ] Mo wá sí ilé
(d) rà IS; + [-----APOR (APAT)] Mo ra aso ní ojà
(e) dàbí: IS; +[--------GB] Ó dàbí kí ó má lo
Ohun tí òfin (27) yìí ń so nip é tí a bá rí òrò-ìse kan, gégé bí elédè, a ó mo sàkáání ibi tí a ti lè bá a. Fún àpeere, (27a) ń so pé rí jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APOR gégé bí àfikún. (27b) náà so pé wá jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APAT gégé àfikún. Kìí se pé àwon òrò-ìse wònyí kò lè yan àfikún mìíràn sùgbón àtúnpínsòrí tí a bá fún òrò kan ni a gbódò tèlé bí béè kó, gbólóhùn tí ó ti je yo kò ní í bófin mú.
Yàtò sí àtúnpínsísòrí tí a menu bà yìí, a tún lè fi òfin ìhun gbólóhùn sàlàyé APIS.
(28) (a) APIS ---> IS
(b) APIS ---> IS APOR
A lè pa méjèèjì pò báyìí:
(29) APIS ---> IS (APOR)
Lóòótó, o dàbí ìgbà pé àwòrán-atóka igi yé ènìyàn ju àkámó asàmìsí lo sùgbón à kò lè so pé òkan dára ju èkejì lo tí a bá fi ojú tíórì wò ó. E se àkíyèsi pé àayè tí àwòrán-atóka igi gbà jut i àkámó asàmì sí lo. Níwòn ìgbà tí ó jé wí pé àwon méjèèjì ni a ó máa bá pàdé nínú ìwé, ó ye kí á mò wón.
(5ii) Òrò-ìse Àsínpò: Lóòótó àwon tètèdé onígíràmà ti máa ń fún gbólóhùn abódé ní oríkì pé òun ni àkójopò òrò tí ó òrò-ìse kan nínú. Èyí kò wolé mó nítorí a ti rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo. Àpeere irú gbólóhùn abode báyìí ni gbólóhùn alásínpò ìse. Gbólóhùn yìí máa ń ní olùwà kan sùgbón àwon òrò-ìse yìí mó ara won. Òfin ìhun gbólóhùn ti a máa ń lò fún àpólà-ìse inú gbólóhùn alásínpò ise ni.
(32) APIS ---> APIS (APISn )
.
Oun tí “n” yìí ń so nip é APIS yìí lè máà níye. E jé kí á wo gbólóhùn kan tí ó ní irú òrò-ìsè yìí.
(34) Adé gbé ògèdè mi fún eran je
(6) Àfòmó:
Ní àárín àpólà ìse àti àpólà orúko ni ìsòrí tí a ń pè ní àfòmó wà. Òpòlopò òrò ni ó wà ní abé ìsòrú yìí. Gbogbo won ni ó sì ní àbùdá òrò-ìse. Ìsòrí yìí ni àwon tètèdé onígírámà ń pè ní asèrànwó-ise. Àwon ohun tí a ń bá lábé ìsòrí yìi ni àsìkò, ibá, múùdù àti ìbámu. Ìdí tí a fi ń pe ìsòrí yìí ní àfòmó nip é púpò nínú àwon ohun tí ó máa ń je yo lábé rè, àfòmó ni wón máa ń jé nínú òpòlopò èdè àgbáyé. Gbogbo èdè ni ó ní àfòmó yìí sùgbón ònà tí èdè kòòkan fi máa ń mú un lò yàtò sí ara won. Gbogbo àwon òrò tí ó wà lábé ìsòrí yìí ní èdè Yorùbá ni ó lè dá dúrò, ìyen ni pé won kì í se mófíìmù àfarahe. Fún àpeere, abé ìsòrí yìí ni a ti máa rí àwon òrò bíi gbódò, lè, máa, ta, ń abll. Pèlú àfòmó tí a ti menu bà yìí, òfin ìhun gbólóhùn tí a ó máa ló ni (35), 936) ni gbólóhùn tí ó lè ti inú rè jáde,
(35) GB ---> APOR AF APIS
(36) Olú gbódò lo
7. Àpólà Atókùn àti Àpólà Àpónlé: A ti menu bà APOR àti APIS. A ti sòrò díè nípa àpólà àpèjúwe àti àfòmó. Àpólà méjì tí ó kù tí a ó menu bà sí i ni àpólà atókùn àti àpólà àpónlé. Òrò atókùn àti APOR ni a máa ń bá nínú àpólà atókùn ni a fa igi sí ní ìdí ní (38). Òfin ìhun gbólóhùn rè ni
(38) (a) Adé lo sí ilé
(b) Mo rí Olú ní ojà
(d) Òjó ti ilé lo sí oko
(39) APAT ---> AT APOR
Òrò àpóné ni a máa ń bá nínú àpólà àpónlé. Òrò àpónlé yìí seé se kí ó ju eyo kan lo ó sì lè jé eyo kan. (41) ni òfin ìhun gbólóhùn àpólà àpónlé Ní (42), a fa igi sí ìdí àpólà àpónlé a sì ya àwòrán-atóka igi fún un ní (43).
(41) APAP ---> AP APAP
(42) Adé lo kíákíá rí
- E rántí pé òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè fó àfòmó sí wéwé ni
AF---> AS, IB, M, IBM.
(8) Orísìí Gbóóhùn Yorùbá: Orísìí gbólóhùn méta ni ó wà ni èdè Yorùbá- (i) gbólóhùn abode, (ii) gbólóhùn oníbò àti (iii) gbólóhùn alákànpò.
(i) Gbólóhùn abode: Púpò nínú àwon àpeere tí a ti ń lò láti ìbèrè ìwé ìléwó yìí ni ó jé gbólóhùn abode. Oríkì tí a lè fún gbólóhùn abode ni gbólóhùn tí ó ní kókó gbólóhùn kan. Ohun tí ó jé kí á lo kókó gbólóhún dipò òrò-ìse ni pé a rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo sùgbón tí ó jé pé kókó gbólóhùn kan soso ni ó ní . Àpeere irú ìyí ni gbólóhùn alásínpò ìse tí a ti sòrò nípa rè sáájú. Òfin ìhun gbólóhùn tí a ń lò fún gbólóhùn abode ni (44); (45) ni àpeere gbólóhùn abódé.
(44) GB ---> APOR AF APIS
(45) Mo ra isu
(ii) Gbólóhùn Oníbò: Gbólóhùn oníbò ni gbólóhùn tí ó ní olórí gbólóhùn àti gbólóhùn àfibò. Olórí gbólóhùn yìí lè dá dúró sùgbón gbólóhùn àfibò kò lè dá dúró.
GB ---> ATAF GB
Òfin gbólóhùn (52) lè gbà wá láàyè láti sèdá.
(53) (a) Olú dé
(b) Ade ra aso
(d) Omo tí ó lo dé
Sùgbón a kò lè sèdá òkankan nínú (54) nípa lílo òfin (52).
(54) (a) Ǹjé Olú dé?
(b) Sé Adé ra aso?
(d) Omo tí ó lo dé bí?
Síbè a ó se àkíyèsí pé àwon gbólóhùn (53) ní nǹkan se pèlú (54). Gírámà tí a pè ní gírámà ìyídà onídàro yìí ní gbára láti se àlàyé ìbásepò tí ó wà láàrin àwon gbólóhùn wònyí. Sùgbón kí a tó menu ba bí yóò se se àlàyé yìí, e jé kí a wo àwon ohun tí a lè bá pàdé nínú gírámà yìí.
10. Gírámà Ìyídà Onídàro:
Ònà méta ni a lè pín gìrámà yìí sí àwon náà ni ìhun ìsàlè, gbé aifa àti ìhun òkè. Àwon èka méjì mìíràn tún wà tí kò ní í je wá lógún púpò nínú ìdánilékòó yìí: àwon náà ni èka fonólójì àti èka ìlárògún (ìní àrògún). A ó wá yè wón won í òkòòkan.
(i) ìhun Ìsàlè: Gbogbo gbólóhùn ni ó máa ń ní ìhun ìsàlè. Ó wá seé se kí ìhun ìsàlè gbólóhùn kan bá ti òkè mu; ó sì seé se kí ó máà bá a mu. Àwon ohun tí a máa ń pá pàdé nínú ìhun ìsàlè ni aká òrò, òfin òrò, òfin gbólóhùn, àttúnpínsìsòrí, òfin ìsòrí òrò, ìyanra (ìyan ara).
(ii) Gbé alfa: Ìtumò gbé alfa ni pé kí á gbé nǹkan kan láti ibì kan lo sí ibòmíràn nínú gbólóhùn.
(iii) Ìhun Òkè: Àwon ohun tí a máa ń bá pàdé nínú ìhun òkè ni ìsòrí kòòfo, gbólóhùn tí a ti da ètò rè rú, ìse lámì kanùn (1ise ní àmì kan ùn) asé.
(iv) Èka Fonólójì: Òkan nínú àwon èka méjì tí kò níí je wá lógún púpò tí a máa ń bá nínú gírámà ìyídà onídàro ni èka fonólòjì. Èka yìí nib í a se ń pe òrò jáde lénu je lógún.
(v) Èka Ìlárògún: Èka yìí náà kò ní í je wá lógún tó béè tàbí jù béè lo nínú ìdánilékòó yìí. Èka yìí ní ó se pèlú àrògún. Òfin síńtáásì lè gba àwon gbólóhùn kan láàyè tí ó jé pé èka yìí ni yóò so pé irú gbólóhùn béè kò ni àrògún. Àwòrán (57) ní ó fi àwon èka wònyí hàn wá dáradára. E jé kí á wá wo bí gírámà yìí se ń sisé.
(11) Gbólóhùn Ìbéèrè béè-ni-béè-kó: Àwon ìbéèrè kan wà tí ó jé pé béè ni tàbí béè kó ni ìdáhùn máa ń jé. Fún àpeere, tí a bá so pé:
(55) Ǹjé Olú lo?
A lè dáhùn wí pé:
(56) Béè ni, Olú lo tàbí béè kó, Olú kò lo
(57) Ìhun Ìsàlè/ìpìlè
aká òrò
òfin òrò
òfin ìsòrí
àtúnpínsìsòrí
ìyanra
òfin ìhun gbólóhùn
Gbé Alfa
Ìhun Òkè
Ìsòrí kòòfo
Gbólóhùn tí a dà ètò rè rú
Ìse lámì kan-ùn
asé
Ẹ̀ká Fonọ́lọ́jì
Ẹ̀ka àrògún
Gégé bí a se so télè, o rorùn láti láti lo òfi ìhun gbólóhùn láti sèdá gbólóhùn bíi (58) sùgbón a kò lè lo òfin ìhun gbólóhùn láti sèdá (55).
(58) Olú lo
Síbè a gbódò lè sàlàyé bí (55) se wáyé. Ohun tí gírámà tí a ń lò nínú ìdánilékòó yìí so ni pé (58) ni ìpìlò (55), ìyen ni pé ní ìhun ìpìlè, (58) nìkan ni a ní. Ìhun òkè ni (55). Ohun tí ó selè nip é léyìn ìgbà tí a ti fi òfin ìhun gbólóhùn sèdá (58) tán ni a wá so atóka ìbéèrè mó on. Bí àwòrán-atóka igi won se rí nìyi.
Àrótì ni AROTI dúró fún. Àwon ìbéèrè mìíràn tí ó bá eléyìí mu tí a sì gbódò sàlàyé won bákan náà ni (61).
(61) (a) Sé Olú lo?
(b) Olú lo bí?
E ó se àkíyèsí wí pé ń se ni àrótì sáájú gbólóhùn nínú Ǹjé Olú lo? Sùgbón nínú Olú lo bí? àrótì yóò tèlé gbólóhùn ni.
(12) Ìbéèrè tí kì í ní ìdáhùn béè ni béè kó: Àwon ìbéèrè kan wà ti ìdáhùn won kì í se béè ni tàbí béè kó. Àpeere irú ìbéèrè béè ni
(63) (a) Ta ni Olú rí?
(b) Kí ni Olú se?
Ònà tí a ń gbà se àlàyé àwon ìbéèrè eléyìí yàtò sí ti béè ni béè kó. A ó rántí pé àrótì, ìyen àwomó ni a lò láti sàlàyé bí ìbéèrè béè ni béè kó se wáyé. Gbé alfa ni a ó fi sàlàyé eléyìí. Nígbà tí a ń sòrò nípa àtúnpínsísòrí òrò-ìse, a sàlàyé pé àwon òrò-ìse bíi: rí àti se gbódò ní APOR gégé bí àbò nínú gbólóhùn tí a bá ti lò wón. Ìyen ni a fi ń rí.
(64) (a) Olú se isé
(b) Adé rí Òjó
Tí (56) kò sì bófin mu
(65) (a) *Adé rí
(b) *Olú se
Sùgbón tí a bá wo (63), a o rí i wí pé APOR kankan kò tèlé rí àti se gégé bi àbò síbè àwon méjèèjì bá òfin mu. Àlàyé tí a rí se ni pé kì í se pé won kò ní APOR gégé bú àbò, won ní ní ìhun ìpìlè. Ìhun òkè ni ó ti dàbí ìgbà pé won kò ní nítorí pé a ti gbé APOR àbò tí wón ní kúrò láàyè won. E se àkíyèsí pé tí a bá ń se ìbéèrè alápèpadà, a máa ń so (66).
(66) (a) Olú se kí ni?
(b) Adé rí tan i?
Nínú gbólóhùn (66), a ò lè so pé se àti rí kò ní APOR àbò nítorí ta àti kí ni ó jé àbò fún òkòòkan won, òrò-orúko sì ni ta àti kí yìí. Àwon òrò yìí ni a gbé kúrò láàyè tí wón wà ní ìhun ìpìlè lo sí ibòíràn kí wón tó dé ìhun òkè. Èyí ló fi dàbí ìgbà pé won kò ní àbò. Ìgbà tí a gbé àwon òrò wònyí kúrò láàyè tí wón wà ní (66) lo sí iwájú ni a ní (63).
Kòòfo ni KF dúró fún. Àwon atóka ìbéèrè kan wà tí òrò-ìse kì í se àtúnpínsísòrí fún won. Àpeere irú won ni:
(68) (a) Níbo ni Olú ti ra aso
(b) Báwo ni Dàda se mú Olu
A ó se àkíyèsi pé àwon òrò-ìse rà àti mú sì ní APOR àbò tí ó ye kí wón ní. Síbè e ó se àkíyèsí pé a lè se àwon ìbéèrè alápèpadà wònyí:
(69) (a) Olú ra aso, níbo?
(b) Dàda mú Olú, báwo?
Ohun tí eléyìí ń fi hàn ni pé (69) náà ni ìpìlè fún (68) sùgbón nǹkan tí ó selè nip é àbé àpólà-ìse kó ni àwon atóka ìbéèrè báwo àti níbo wà. Abé ìsòrí tí wón wà ni a ń pè ní àrótì. Bí àwóràn-atóka igi ti won se rí nì yí.
Tí a bá lo atóka ìbéèrè tan i tàbí kí ni láti bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko olùwà, ààyè olùwà yìí kò ní í jé kòòfo. A ó fi arópò orúko kan sí ààyè yìí. Béè náà nit í a bá bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko tí ó ń yán òrò-orúko mìíràn. Àpeere.
(71) (a) Olú gbé ìwé Adé
(b) Ta ni ó gbé ìwé Adé?
(d) Ta ni Olú gbé ìwé rè
13. Awé gbólóhùn Asàpèjúwe:
Gbólóhùn tí a tún máa ń gbé alfa nínú rè ni awé gbólóhùn asàpèjúwe.
Àbùdá Awé gbólóhùn Asapèjúwe:
i. A rí APOR tí awé gbólóhùn oní-tí tèlé
ii. APOR tí ó saájú awé gbólóhùn oní-tí yìí ni olórí fún gbogbo
awé gbólóhùn yìí.
iii. Àlàfo kan wà nínú gbólóhùn àfibò inú awé gbólóhùn yìí.
iv. Kò sí ibi tí a kò ti lè rí àlàfo tí a menu bà ní (iii) yìí.
AGBA dúró fún awé gbólóhùn asàpèjúwe.
(vi) Àlàfo tí a menu ní III gbódò ní àmì kan náà pèlú atíka awé gbólóhùn asàpèjúwe.
(vii) Àwon kan wà nínú àwon awé gbólóhùn asàpèjúwe tí kì í ní àlàfo. Àwon yìí ni ìgbà tí a bá se àpèjúwe fún APOR olùwà àti OR tí ó bá yán OR mìíran.
(viii) Ó pon dandan kí APOR méjì bá ara mu nínú awé gbólóhùn asàpèjúwe. Àwòrán-atóka igi tí ó sàlàyé awé gbólóhùn yìí nì yí ní sí-sè-n-tèlé
GB gbódò ní APOR tí ó bá ti iwájú rè dógbà nínú
Àmì yìí I ń fi hàn pé àwon APOR méjèèjì bá ara mu. A ó so APOR; kejì di ti a ó gbé e wá sí abé àfikún.
Omo ni a ó gbé wá sí abé àfikún tí yóò di ti.
(14) Òrò-Ìse aláìléni:
A ó se àkíyèsí pé gbogbo nǹkan tí a ti ń gbé, apá òtún ni a ti ń gbé won wá sí apa òsì. Ìbéèrè wá nip é sé apá òsì nìkan ni a máa ń gbé nǹkan wa. Ìyen ni pé se apá òsì nìkan ni a máa ń gbé ‘alfa’ wa ni? Kì í se apá òsì nìkan. Àpeere tí a ó fún wa báyìí yóò fi èyí hàn. Àpeere náà ni gbólóhùn tí ó bá ní òrò-ìse aláìléni nínú. Irú gbólóhùn béè ni:
(76) Kí á pa àgó méta dára,
dára tí ó wà nínú gbólóhùn yìi ni a pè ní òrò-ìse aláìléni. Àwon òrò-ìse mìíràn tí ó tún wà lábé ìsòrí yìí ni burú, dájú, dùn, wù abbl. E ó se àkíyèsi pé ìtumò kan náà ni (76) àti (77) ni. (77) ó dára kí á pa àgó méta. Níwòn ìgbà tí wón tin í ìtumò kan náà tí òrò inú won sì férè bára mu tán, ó ye kí á lè topa ìpìlè won dé ibì kan náà. (76) ni ó jé ìpìlè fún (77). Ohun tí ó selè ni pé a gbé kú á pa àgó méta lo sí èyìn dára. Nígbà tí a se eléyìí, ààyè ibi tí kí á pa àgó méta wà télè wá sòfo. Ààyè olùwà ni ààyè yìí. Níwòn ìgbà tí ààyè olùwà kò sì gbódò sófo, a wá fi ó tí kò tóka sí enikéni sí ààyè náà. Báyìí ni a se rí (77) láti ara (76).
Àyè kòòfo (KF) yìí ni a ó wá fi ó aláìléni sí. Apá òsì ni a ti gbé nǹkan lo sí apá òtún. Àpeere àwon gbólóhùn tí ó se báyìí wáyé ni:
(80) (a) (i) Kí á jalè kò dára
(ii) Kò dára kí á jalè
(b) (i) Pé mo pé dùn mí
(ii) Ó dùn mí pé mo pé
(15) Gbólóhùn Àse:
Kì í se gbogbo ìyídà ni ó máa ń ní gbé ‘alfa’. Ìyen ni pé kì í se gbogbo ìyídà ni a máa ń gbé nǹkan láti ibì kan lo sí ibòmíràn. Àpeere gbólóhùn tí a sèdá láìgbé nǹkan kan lo sí ibòmíràn ni gbólóhùn àse. Àpeere gbólóhùn àse ni:
(18) (i) wá
(ii) jókòó
(iii) Dìde
Gbólóhùn ni àwon wònyí sùgbón wón jo APIS lásán. Òhun tí ó selè ni pé a ti pa APOR olùwa won je. APOR olùwà ti a sì pa je ni iwo. Ohun tí a fi mò pé ìwo ni a pa je ni pé a máa n lò ó nínú gbólóhùn àkésí.
(82) Ìwo, wá
Àwon èrí mìíràn tí ó fi ìdí rè mule pé enikejì eyo ni a pe je ni ìwònyí. Nínú gbólóhùn alátapadà, eni nínú APOR àbò gbódò bá eni nínú APOR olùwà mu. Ìyen nip é tí APOR olùwá bá jé eni kìíní eyo, béè náà ni APOR àbò gbódò jé. Fún àpeere, ibì tí àwon gbólóhùn alátapadà (b) ti wa ni (a)
(83) (a) *Òjó féràn Òjó
(b) Òjó féràn ara rè
(a) *Èmi féràn èmi
(b) Èmi féràn ara mi
Òjó àti ara rè jé eni kéta eyo. Èmi àti ara mi náà sì jé eni kìíní eyo. E jé kí á wá wo gbólóhùn àse.
(84) Ìhun ìpìlè: *Ìwo gbádùn ìwo
Alátapada: Ìwo gbádùn ara re
Yíyo Olùwà: Gbádùn ara re
Bí òfin yìí se sísé ní sísè-n-telé ni eléyìí. Èrí kejì nit i orísìí ìbéèrè kan tí a lè se lórí gbólóhùn àse. Ìbéèrè yìí fi hàn gbangba pé eni kejì eyo ni a pe je.
(85) (a) Mú owó bò lóla / Sé o gbó?
(b) Wá sí ilé wa o / Sé o gbó?
Ìbéèrè yìí fi hàn pé èni kejì eyò ni a ń tóka sí.
(16) Òté tí ó de Gbe ‘alfa’: A ti sàlàyé pé ìtumò gbé ‘alfa’ ni pé ki a gbe nǹkan tí ó bá wù wá láti ibi kan lo sí ibòmíràn. Òté wà tí ó de nǹkan ti a lè gbé.
(1) A kò lè gbé òrò kankan láti inú gbólóhùn tí ó bá jé pé APOR tí o ní olórí ni ó je gàba lé e lórí.
Fún àpeere, láti inú àwon àpólà tí a fa ìlà sí ní ìdí yìi, a kò lè gbé òrò kankan.
(87) (i) (a) Ìròyìn pá Nàìjirià gba góòlù dùn mó mi
(b) *Kí ni ìròyìn pé Nàìjíríà gbà – dùn mó mi?
(ii) (a) Olú se ìlérí pé òun yóò fún un ní ìwé
(b) *Kí ni Olú se – pé oun yóò fún un ní ìwé?
(iii) Tí olùwà gbólóhùn bá jé gbólóhùn, a kò lè gbé nǹkan kan láti inú rè.
A kò lè gbé nǹka láti inú gbólóhùn tí a fa igi sí ní ìdí wònyí.
(89) (a) (i) Síse ìdáwò mérin ni ojó kan dára
(ii) *Kin i síse ____ ni ojó kan dára?
(b) (i) Kí á pa àgó méta wù mí
(ii) Kí ni kí a pa ¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬___ wù mí?
A kò lè gbé nǹkan kan láti inú àpólà tàbí gbólóhùn àso.
A kò lè gbé eyo nǹkan láti inú àpólà ti a fi ìlà sí ní ìdí yìí.
(91) (i) Mo ri Òjó àti Adé
(ii) *Ta ni mo rí Òjó àti Adé
(iii) * Ta ni mo rí _________ àti Adé?
Tí a bá máa gbé nǹkan kan, méjèèjì ni a ó gbé papò.
(92) Ta ni mo rí _____________?