Segun Arinze Listen (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Segun Padonou Aina,[1] tí wọ́n bí ní ọdún 1965) jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdẹ̀ Nàìjíríà[2] àti òǹkọrin.[3][4][5][6][7]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
Òun ni àkọ́bí láàárín àwọn ọmọ méje tí Lydia Padonu bí.[8] ÌlúBadagry, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ló ti wá. Ilé-ìwé Victory College of Commerce ní Ilorin ló lọ, kí ó tó wá lọ sí Taba Commercial College ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná láti parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Dramatic Arts ní Obafemi Awolowo University. Ó gba orúkọ ìnagijẹ Black Arrow làtàrí ẹ̀dá-ìtàn tó ṣe nínú eré ọdún 1996 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Silent Night" èyí tí Chico Ejiro gbé jáde.[9][10]
Ó fẹ́ òṣèrébìnrin ẹgbẹ́ rẹ̀, tórúkọ rè ń jẹ́ Anne Njemanze, àmọ́ ìgbéyàwọ́ yìí ò pẹ́ rárá.[11] Tọkọ-taya náà bímọ obìnrin kan, tí wọ́n sọ ní Renny Morenike, tí wọ́n bí ní ọjọ́ 10, oṣụ̀ karùn-ún.[12]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
Segun Arinze bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó yàn láàyò gẹ́gẹ́ bí i akọrin àti òṣèré. Orin kíkọ ló kọ́kọ́ gbe síta gbangba, lẹ́yìn ṣàbéjáde orin kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Dream.[13] Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú fíìmù àgbéléwò ní ìlú Ilorin. Yàtọ̀ sí iṣé òṣèré tó yàn, Segun tún jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́ṣe-fíìmù, tó sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú African international film festival, tó sì ń fún àwọn ìran òṣèré tó ń bọ̀ lẹ́yìn mu nínú omi ìmọ̀ rẹ̀.[14][15][16]
Àṣàyàn fíìmù rẹ̀
- Across the Niger
- Silent Night
- Chronicles (pẹ̀lú Onyeka Onwenu àti Victor Osuagwu)
- Family on Fire (2011)
- A Place in the Stars (2014)
- Invasion 1897 (2014)[17][18]
- Deepest Cut (2018) - pẹ̀lú Majid Michel àti Zach Orji
- The Island Movie (2018)[19]
- Gold Statue (2019)
- Òlòtūré (2019)
- She Is (2019)
- Who's the Boss (2020)
- Blood Sisters (2022)
- Blogger's Wife (2017)
- Highway to the Grave (1999)
Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
Àwọn ìtọ́kasí