Salamatu Hussaini Suleiman jẹ́ agbejọ́rọ̀ tí ó sì jẹ komísọ́nà lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, àlàáfíà àti àbò fún ẹgbẹ́ ECOWAS.[1] Ní oṣù kejìlá ọdún 2008, wọ́n fi jẹ mínísítà lórí ọ̀rọ̀ obìnrin àti ìdàgbàsókè ìlú.[2][3]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
Wọ́n bí Salamatu Hussaini Suleiman sí ìlú Argungun ní ìpínlẹ̀ Kebbi. Bàbá rẹ̀ jẹ́ adájọ́, ìyá rẹ sí wá láti ìdílé ọba ní Gwada. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Queens College ni Èkó. Ó tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Ahmadu Bello University ní ìpínlẹ̀ Zaria, ó sì gboyè nínú ìmò òfin.
Iṣẹ́
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú Ministry of Justice ní ìpínlẹ̀ Sókótó. Lẹ́hìnńà ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé ìfowópámọ́ Continental Merchant Bank ní ìlú Èkó fún ọdún méje. Ó siṣẹ́ pẹ̀lú NAL Merchant Bank fún ìgbà díè kí ó tó lọ sí Ilé iṣẹ́ Aluminium Smelter Company níbi tí ó ń tí ṣe onímòràn òfin fún wọn.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Umaru Yar'Adua fi Suleiman jẹ mínísítà lórí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ní oṣù kejìlá ọdún 2008.[4][5]
Àwọn Ìtọ́kasí