Odò Congo River, tí àwọn ènìyàn mọ̀ tẹ́lẹ̀rí sí Odò Zaire, ní odò kejì tí ó gùn jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà, odò Nile nìkan ni ó kéré jùlọ. Ó tún wà lára àwọn odò tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé. Òun ni odò tí ó jìn jùlọ ní àgbáyé, jíjìn rẹ̀ tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ okòó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rin(720).[1] Gígùn odò Congo tó 4,370 km (2,715 mi).
Orúkọ
Orúkọ odò náà, Congo/Kongo wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Kongo tí wọ́n ti fi gúúsù etí odò náà ṣe ilé rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ àwọn ẹ̀yà tí ó ń gbé ibẹ̀ yìí sí "Esikongo".[2]