Niger Delta swamp forests (èdè Yorùbá: igbó irẹ̀ Niger delta) jẹ́ igbó erẹ̀ kan ní apa gúúsù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ àwọn igbo irẹ̀ nínú omi tí ó mọ́ kongá ní Niger Delta ti odò Niger. Òun ni igbó irà tí ó tóbi jùlọ ní Áfríkà lẹ́yìn igbó irà Congo.[1][2][3][4] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ìlú wà ní agbègbè igbó náà, àwọn ènìyàn kò gbé ní ibi ẹ̀ nítorí ó ṣòro láti kó ilé tàbí ọ̀nà kọjá irà náà, ṣùgbọ́n , èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ nítori pé àwọn ilé isé epo ti ń wa kùsà epo ní ilẹ̀ irà náà.
Ibi tí ó wà
Niger Delta swamp forest wà ní etí Odò Niger. Etí gúúsù rẹ̀ jẹ́ bi kìlómítà mẹ́wá láti Gulf of Guinea. Ìlú Port Harcourt wà ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.
Àwọn agbègbè tí ó wà ní abé àbò
Ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ yìí ló wà lábẹ́ àbọ̀ ìjọba, àwọn agbègbè yìí sì wà nínú àwọn igbó tí wọ́n ti ń gégi tà.[3]