National Museum of Ghana wà ní olú ìpínlẹ̀ Ghana, ìpínlẹ̀ Accra. Òun ni èyí tí ó tóbi jù tí a sì kọ́kọ́ sẹ̀dá nínú àwọn musíọ́mù tí ó wà lábẹ́ ìdarí Ghana Museums and Monuments Board (GMMB).
Wọ́n sí musíọ́mù náà kalẹ̀ ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹta ọdún 1957 gẹ́gẹ́ bi ara ayẹyẹ ìgbòmìnira Ghana. Duchess of Kent, Princess Marina ló ṣe àfilọ́lẹ̀ rẹ̀. Adarí àkọ́kọ́ musíọ́mù náà ni A.W. Lawrence.[1]
Àwọn ohùn ayé ọjọ́ ọ̀hún tí wọ́n wú nílẹ̀ àti àwọn àwòrán wà nínú musíọ́mù náà.
Àwọn ohun tí ó wà nínú musíọ́mù náà
Musíọ́mù náà jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ǹkan ayé àtijọ́ tí wọ́n padà wú jáde nínú ilẹ̀, àti àwọn ǹkan bi ohùn èlò orin ti órilè èdè Ghana, àwọn aṣọ Ìbílẹ̀, àwọn ǹkan tí wọ́n fi àmọ̀ ṣe láyé ọjọ́, àwọn eré àti oríṣiríṣi àwọn àwòrán.
Àwọn Ìtọ́kasí
- ↑ R. M. Cook, ‘Lawrence, Arnold Walter (1900–1991)’, Oxford Dictionary of National Biography, Oxford University Press, Sept 2004; online edn, May 2009