Napoléon Bonaparte[lower-alpha 1] (15 August 1769 – 5 May 1821) jẹ́ olórí ológun àti adarí òṣèlú àti ọmọ bíbí ìlú Corsica ní ilẹ̀ Faranse. Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká ní àsìkò ìyípadà ìṣèjọba ilè Faranse, tí ó sì léwájú àwọn ìjangbara oríṣiríṣi ní àsìkò ogun. Gẹ́gẹ́ bí Napoleon I, òun ni ọba ilẹ̀ Faranse láti ọdún 1804 sí ọdún 1814, àti 1815. Napoleon ṣe àkóso ìjọba ilẹ̀ Yuroopu àti àgbáyé fún bí ọdún mẹ́wá, nígbà tí ó ń léwájú nínú àwọn ogun oríṣiríṣi tí a mọ̀ sí Napoleonic Wars. Ó ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun, tí ó sì borí àwọn ogun tí ó sì mu láti gba àwọn ilé lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìjọba Faranse, tí ó sì darí ilẹ̀ Yuroopu lápapọ̀ ṣáájú kí ìjọba rẹ̀ tó ṣubú ní ọdún 1815. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí ní orílẹ̀ àgbáyé tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣèjọba rẹ̀ jákè-jádò àgbáyé. Ó sì wà nínú àwọn adarí tí ó gbayì jùlọ ní inú ìtàn àgbáyé. [2]
Ìtọ́ka sí
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref>
tags exist for a group named "lower-alpha", but no corresponding <references group="lower-alpha"/>
tag was found