Eṣinṣin Ilé tí wọ́n ń dà pè ní (Musca domestica) jẹ́ ohun tí ó ń fò, tí ó sì jẹ́ ọ̀ksn lára ẹbí Cyclorrhapha. Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé eṣinṣin yí wá láti ayé Cenozoic, kí ó tó na fọ́n ká sí orílẹ̀ àgbáyé. Ó jẹ́ ọ̀kan lára kòkòrò tí ó wọ́pọ̀ nínú Ilé. [1]
Ìrísí rẹ̀
Eṣinṣin ilé tí ó bá ti dàgbà ma ń ní àwọn olómi eérú sí àwọ̀ dúdú, tí ó sì ní ìlà olóòró ní ẹ̀yìn, ó nírun wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́ lára, pẹ̀lú ìyẹ́ méjì. Wọ́n ní ojú pupa tí yọ kòngbà síta. [2][3]
Ìbálòpọ̀ ìyẹ́yin àti ìpamọ rẹ̀
Eṣinṣin ilé tí ó jẹ́ abo ma ń sábà ní àṣepọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan, tí ó sì ma ń gbé àtọ̀ akọ kiri láti lòó nígbà tí àsìkò àti yẹ́yin bá tó. Ó ma ń yé ẹyin tí ó tó ọgọ́rùn ún nípa sísàba lé ohun kan tí ó ti ń jẹrà bí ónjẹ bíbàjẹ́ tàbí ìgbẹ́. Àwọn ẹyin yí ni wọ́n ma ń yíra padà sí ohun abẹ̀mí tí kò lẹ́sẹ̀ tí a mọ̀ sí [[[ìdin]].[4]
Àwọn Ìtọ́kasí