Atumo-Ede (Yoruba-English): E
Oju-iwe Kiini
each:pro; (Each of them will go.) lúkúlùkù; ọ̀kọ̀ọ̀kan olúkúlùkù won yóò lo.
eager: (He was eager for success.) ní aápon; ní ìtara ó ní ìtara fún àseyege.
eagernes: n; (I was surprised at his eageness to ruturn.) aápon; ìtara mo ní ìyàlénu fún aápon rè láti padà.
eagle: n; (The hunter killed an eagle.) eye ìdì ode náà pa eye ìdì kan.
ear: (The doctor looked into my ears.) etí onísègùn náà wo inú àwon etí mi
earl: n; (The man was made as an earl.) irúfé oyè kan ní ilè àwon òyinbó –igbá kerun mógàjí wón fi okùnrin náà se ligbákerin mógaji.
early: adj; (He is in his early twenties.) ní kùtùkùtù; ní ìbèrè ó sese wà ní ìbèrè ogún odún rè.
early: adv; (The bus arrived very early.) tètè okò náà tètè de.
earn: v; (He earned for the work he did.) gba owó ó gba owó fún isé tó se.
earner: n; (The man is high wage earner.) ení tí ó n gba owó fún isé owó nlá ni okùnrin náà n gba.
earnest: adj; (The man married an earnest woman.) ní ìgbónára; ní ìfokansí okùnrin náà fé obìnrin tí ó ní ìtara.
earnest: n; (The publicity campaingn will begin in earnest.) ìtara; ìgbónára. Ipolongo gbángba yóò bèrè nínú ìtara/ìgbonára.
earring: n; (She lost her earring.) yetí; òruka etí ó so òrùka etí rè nù
earth: n; (The moon goes round the earth.) (He filled the hale with earth.) ayé òsùpá máà n yípo aye. Ilè; yèpè Ó fi yèpè dí ihò náà.
earthquake: n; (The earthquake struck shortly after 5pm.) ilè ríri Ile ríri náa sele léyìn aago marùn-ún Ìròlé gáún.
ease: n; (He passed the exam with ease.) iròrun; ìrora; ìdèrùn ó yege nínú ìdánwò náà pèlú ìròrùn.
ease: v; (He tried to ease the burden of the debt.) mú rorun; dín inira ku o gbìyànjú àti mu ìnira gbese náà dìnkù.
easel: n; (The capenter made an easel.) igi tí a n fi àwòrán kó igi tí a n gbé pátáko ìkòwé lé. Gbénàgbénà náà se igi tí a n fi àwòrán kó kan.
easily: adv; (I can easily finish tonight.) pèlú ìròrùn mo le parí rè ní àsálé pèlú ìròrùn.
east: n; (The wind is blowing from the east.) ìlà-oòrùn. Aféfé n fé láti ìlà-òòrùn
easter: . (They went on easter holiday.) àjínde wón lo nínu ìsìmi odún àjínde
easy: adj; (The place is easy to reach.) rorùn; láìsoro ó rorùn láti dé ibe.
eat: v; (He was too ill to eat.)
jẹ. Ara rè kò dá ju kí ó jemi lo
eaves: n; (The binds are resting under the eaves.) ìgbàsòòrò; enu òsòòrò ilé. Awọn eye n ko ìté won sí enu awon òsòòrò òrùlé náà.
ebb: v; (Our enthusiasm soon began to ebb.) fà; sá Ifé okàn wá tí fé bere sí ní sá/fà.
ebb: n; (The tide is on the ebb.) fí fà omí náà ti n di fífà.
echo: n; (The cave has a wonderful echo.) gbohùngbohùn Ihò náà ní gbohùngbohùn to yaní lénu.
echo: v; (Their shouts echoed through the forest.) se gbohùngbohùn Igbo náà se gbohùngbohùn ariwo wọn.
eclipse: n; (There was an eclipse of sun last week.) ìsíjibò; ìmúsókùn; ìwòòkùn Ìwòòkan oòrùn wáyé lósè tó kojá.
eclipse: v; (The sun is partly eclipsed by the moon.) sí ìjibò; mú wòòkùn ósùpá náà síjo bo òòrùn ní apá kan.
edge: n; (He went down to the water’s edge.) igún etí ó lo sí etí odò náà
edge: v; (They edged the road with grasses.) se igun sí; fe etí sí. Wón se igun sí ojú ònà náà pèlú koríko.
educate: v; (She was educate in france.) tó; kó; kó la ní èkó. Wón kó o ní èkó ni ilè faransé.
education: n; (He gave his son education.) ekó ó fún omo rè ní èkó.
eal: n; (He was as slippery as an eal.) eja afarajejò ó n yó lára bí eja afarajejò.
effect: n; (The experience had a profund effect on her.) èrè; ìyorísí Irírí náà ní ìyorisí gígìgìdi nínú ayè rè.
effect:v; (The tablets effected a cure on her.) fa àyípadà ; mú ayípadà bá. Awon oògùn oníkóro náà mu ayípadà ìwòsàn bá a.
effort: n; (They made effort to finish on time.) ìyànjú wón gbìyànju làti tètè parí lákòólò.
egg: n; (Egg is fragile.) eyin Nnkan elegé ni eyin.
elastic: adj; (The rubber is very elastic.) tí o lè lò; lílò Róbà náa n lò dáadáa.
elbow: n; (He hit me with his elbow.) ìgbònwó’ìgúnpá ó fi ìgbònwó re gbá mi.
elder: n; (The man is an elder.) ègbón; àgbà; alàgbà Alàgbà ni okùnrin náà.
electricity: n; (Don’t leave the lights on-it wastes electricity.) ohun amúnáwá Ma se tan ina sílè o n fí ohun amúnáwa sòfùn
elephant: n; (The hunter killed an elephant.) erin; àjànàkú ode náà pa erin.
elf: n; (There were elves in the forest.) kúrékùré; iwin. Àwon kúrékúré/iwin wà nínú igbó náà.
elsewhere: adv; (Our farourite restourant was full so we had to go elsewhere.) níbòmíràn Ilé oúnje tí a nífèé kún, a ní láti lo sí ibòmíràn.
embarrass: v; (Are you trying to embarrass me?) fi se eléyà; fi sèsín se ó fé máa fi mi sèsín ni?
embroider: v; (She embroidered flowers on the cushion.) fi abéré sonà sí lára ó fí abéré se oná olódòdó sí àga onítìmùtìmù lára.
emerald: n; (He gave me an emerald stone.) irúfé òkúta iyebíye kan ó fún mi ni okuta iyebíye.
emperor: n; (The emperor is dead.) oba nla kan; olùdarí opolopò ìlú olùdarí òpòlopo ilé náà ti kú.
employ: v; (The company employs mainly.) gbà sí isé Àwọn obìrin nìkan ni ilé-isé náà máa n gbà sísé. woman
empress: n; (The emperor came with his empress.) aya oba nlá olùdarí opòlopò ilú náà wé pèlú aya rè.
empty: adj; (He gave me an empty box.) kòròfoó fún mi ní kòròfo ìsáná.
empty:n; (Take your empties to the bottle bank.) ohun to jé kòròfò; àwọn kòròfo nnkan kó àwon kòròfò ìgò re lo sí ibi ìkógò pamo só.
empty: v; (He emptied the box.) so di kòròfo ó so àpótí náà di kòròfo.
enamel: èròjà adám-bíi-díngí Díè lára èròjà adán-bíi-dingí ara abó yìí tí bó kúrò some of the enamel on this pan has chipped off.
enamel:v; (He enamelled jewellery.) fi èròjà adán-bíì-díngí se ó fó èròjà adán-díngí se nnkan osó
enclose: v; (I will enclose your application with mine.) fi nnkan sínú àpò iwe Màá fi iwé ìbèbè fún isé re sínú àpò ìwé pelu tèmi.
encourage: v; (Her parents always encourage her in her studies.) (Don’t encourage bad habits in a Child.) fún ní ìwúrí; kì laya. Awọn òbíi rè máa n fún un ní ìwúrí nínú èkóo rẹ̀ Mú pò si; mú gbòòrò sí Má se mú ìwà búbúru omo pò sí omodé.
encouragement: n; (People need encouragement to try something new.) ìyànjú; ìwúrí. Àwon ènìyan nílò ìwúrí láti le gbìyànju ohun òtun
encyclopedia: n; (He bought an encychopedia of music ìwé yaágbo-yaájù atímò òrò ó rá ìwé yáagbó-yaáju tí o je mó orin.
end: n; (We came to the end of the road.) òpin A de òpín ònà náà.
end: v; (How does the story end?) parí dé òpin Bawo ni ìtàn náà se parí?
endurance: (He showed remarkable endurance throughout his illness.ìpamóra’ìforítì. Ó fi ìpamóra tó le han fún gbogbo ìgbà to fi wà nínú àìsàn
endure: v; (He endured three years in prison for his religious beliefs.) forítì; pa móra; fara dà.Ó fara dà a fún odùn méta ní ogbà èwon nítorí ìgbàgbo nípa èsìn rè.
enemy: n; (His arrogance made him many enemies.) òtá Igbéraga rè jé kí ó ní òpò òtá
engage: v; (He wants to engage a new secretaty.) (Battle was engaged.) (The man was engaged with modern art.) (The two cog-wheels engaged ang the machine started.) gbà sísé ó fé gba akòwé túntun sí isé. Bèrè: Ìjà/ogun bèrè Wà pèlú: Okùnrin náà wà pèlú àwon onà ayé òde òni. so pò; wà po. Eyin kèkè méjèèjì náà wà èro náà bèrè sí ní sisé.Rí ààyè fún. N kò rí ààyè fún òrò èyìn. I have no time to engage in gossip.
engaged: adj; (They are engaged.) tì bá se adéhùn ìgbeyàwó. Wón ti bara se adéhùn ìgbeyàwó
engine: n; (My car had to have a new engine.) èro okò ayókélé mi ti ye kí o ní èrò tuntun.
engineer: n; (My fathef is an engineer.) amoju èro; atun-ero-se Amojú èro ni bàbà mi
enjoy: v; (enjoyed the evening enormously.) gbádùn Mo gbádùn ìròlé yen dóba
ejoyment: n; (She lives only for enjoyment.) ìgbádùn ó kan wà fún ìgbádun sáa ni.
enormous: adj; (He gave me enourmous amount.) tobi púpò; pò púpò ó fún mi lówó to pò púpò of money.
enough:adj; (Have you made enough copies?) tí ó tó se o ti se èdà tí o tó ?
enough: adv; (She is old enough to make her own decisions.) tó ó ti dàgbà tó láti dá èrò ara rè pa.
enquire:v; (How long have you been with the company? He enquired) bèère; tose; wádìí o ti wà pèlú ilé isé náà ti pé tó ? ó bèèrè.
enter: v; (He entered his room.) wò; wole; wonú o wonu ìyèwù rè
entertain: v; (I don’t entertain very oftern.) (Could you entertain the Childern for an hour.) se ní àlejò. N kíì sàlejò ní gbogbo ìgbà Dá lára yá. N jé o lè dá àwon omo náà lára yá fún wàkàtí kan
entertainment: n; (He went to the place of entertainment.) idanilárayá ó lo sí ibi idániláraya náà.
enthusiasm: n; (He has ability to generate enthusiasm in others.) ìwúrí ó lágbára láti máa fún àwon ènìyàn ní ìwúrí.
enture: adj; (The entine village was distroyed.) gbogbo; odindi. Gbogbo abúlé náà ni wón bàjé.
entrance: n; (The Child sat at the entrance of the house.) àbáwolé omo náà jókòó ní abáwo-inú ile nàá.
entry: n; (The thieves had forced an entry into the building.) (There is no entry in his dary for that day.) (Painting is my entry for the art competetion.) ìwole; wíwolé. Awon olè náà fi ipá wo inú ilé náà. ohun tí a ko sínú ìwé kó sí ohun tí ohun tí wón ko sínú tí o n ko isèlè ojoojumo síi rè. Eni tí ó n díye tàbí ohun tí a n dije fún Nnkan kíkùn ni mo n se ìdíje lé lóri nínú ìdiye olónà sise náà
Oju-iwe Keji
envelolpe: n; (He put the letter in an envelope.) àpò-ìwé ó fi léta náà sínú àpò ìwé. envelope: v; (The mountain was envoloped in cloud.) bò pátápátá kùrukùru bo òkè náà
envy: v; (I have always envied her easygoing attitude to life.) jowu mo ti máa n jowu bí o ti maa n lo jéé.
envy: n; (His colleagues were full of envy.) owú Awon elegbé rè kún fún owú
episode: n; (That is an episode in my life I would rather forget.) ìsèlè; ìtàn; abala ìtàn. Ìsèlé tí n kò jé gbàgbé láyè mi niyen.
equal:adj; (They are of equal height.) bara mu dógba Wón ga bára mu
equal:n; (She is the equal of her brother as far as intelhgence is concerned.) ogbà; egbé; irò Ogbà ni oun pèlú egbón re nínu bí làákaye ti mo.
equal: v; (Nobody else can equal him in ability.) bá dógba; bá mu kò tún sí eni tó lè bá a dógna ni lilágbara àtise.
equator: n; (It is often very hot near the equetor.) ila àyíká tí ó dá ayé sí méjì ogboogba Ibi ìlà tí ó dá ayé sí méjì ogboogab máa n sábàá gbóna.
equip: (They equiped themselves for the expedition.) pese-pèsè ohun èlò fún Wón pèsè fún ara won fún ìrìn-àjò náà.
equipment: n; (We need office equipment.) ohun èlò A nilo awon ohun elò ibi isé.
errect: adj; (The dog’s ears were errect and alert.) nàró; dúró; lóòro. Àwon eti aja nàró ó dúró wáwá.
errect: v; (The pillar was errected.) gbéró; kò. Wón gbe òwòn nàá ro
errand: n; (I have come on a special errand.) isé reran Isé rírán pàtà kan ló gbe mi wá.
error: n; (He corrected his errors.) àsìse ó tún awon àsìse rè se
escape: v; (Two prisoners have escaped.) yo; bó lówó. Àwon eléwòn méjì ti bó.
esacpe: n; (He made his escape when the guard’s back was turned.) (The two escapes have left this country.) ìyo-nínú-nnkan; ìbólówó-nnkanó rí ìyokúrò nígbà tí olùsó náà ko èyìn síi. ení tí ó yo tàbí bó lówó nnkan (ogbà èwòn) Àwon méjèèji tó yo nínú èwòn náa ti sa kuro lórílè-èdè yìí.
especial: adj; (He gave her especial care.) pàtàkì; pàápàá ó fún ni ìtóju tí ó se pàtàki.
especially: adv; (I love this country, especially in spring.) pàápàá jùlo. Mo feran oríle-èdè yìí pàápàá jùlo nigba ooru.
estimate: v; (Try to estimate how mach you will pay out over the coming year.) síro. Gbìyànjú kí o sírò iye tí wà á san jade fún odun ti n bo.
estimation: n; (In my estimation, he is the more suitable condidate.) ìdíyele; ìsòdiwon; isirì. Nínú ìsòdìwon tèmi òun leni tó dára ju.
eve: n; (Last year Christmas eva was very interesting.) àsálé tó saáju àkànse odún kan tabi ètò kan. Asale odún kérésì odun tó kojá dun.
even: adj; (The stitches weren’t very evern.) tí o téju; tí ó dógba ojú awon lílè náà kò dógba dáadáa.
even: adv; (He didn’t answer even ‘my letter.) sì tún; pàápàá ko dáhùn kankan rárá pàápàá létà mi.
even: v; (Chelsea evened the score just half time.) mú bá dógba. Chelsea ami ayò náà dógba ní abala kejì ìdíye náà.
evening: n; (I will come and see your tomorrow evening.) ìròlé; àsálé. N ó wá rí o ní alé òla.
event: n; (No event no history.) ìsèlè. Láìsí ìsèlè kò lè sí ìtàn
ever: adv; (Have you ever seen an elephart?) (Paul, ever the optimist agreed to give it one last try.) (She told me she would love me for ever.) rí. N jé o ti rí erun rí ? Ní gbogbo ìgbà. Póólù eni tí ó máa n ní ìrètí mí gbogbo igba; gbà lati gbìyànjú léèkan sí i. láéláe ó so pé oun yóò fé mí títí laelae.
evergreen: n; (Big animals ara found in evergreen forest.) igi tí o n ní ewé tútù yípo odún A máa n rí àwon eranko nlá nínú igbó tí ewe igi won n tutù kádún.
every: adj; (I have not read every book on methematies.) olúkúlùkù; gbogbo. N kò tíì ka gbogbo ìwé lórí ìsiro.
everybody: n; (Everybody loves him.) gbogbo ènìyàn; olúkúlùkù. Gbogbo eniyan ló féran re.
everyday: adj; (The book is for everyday use.) Iwe náà wà fún ilo ojoojúmó
everyday: adv; (He sings everyday.) lójoojúmò ó máa n korin lójoojúmò.
eveyone: n; (She ignored everyone else) gbogbo ènìyan ó pa gbogbo eniyan tó kù ti.
everything: n; (She did everything he told her.) ohun gbogbo ó se ohun gbogbo tó sò fún un.
everywhere: adv; (He follows me everyday.) ibi gbogbo ó máa n tè lé mi lo sí ibi gbogbo.
evil: n; (You cannot pretent there is no evil in the world.) bìlísì; ibi o kòlè maá se bí emi pé kò sí ibi láyé.
evil: adj; (The man has evil spirt.) buburu okunrin náà ní èní búburú.
ewe: n; (I have an ewe.) omo àgùntan Mo ní omo àgùntan kan
exact: adj; (He gave me the exact book.) gan-an ó fún mí ni iwe náà.
exactly: adv; (This is exactly what I expected.) gàn-an; gégé; wékú ohun ti mo retí gan-an nìyí.
exaggerate: v; (He always exaggerate to make his slories more amusing.) so asorégèé ó máa n so àworégèé kí ìtan rè ba lè pani lérìn-ín.
examination: n; (He has done the entrance Examination.) (Further examination it was found that the signetire was not genuines) ìdánwò; wadìí nípa ìbèére; ó ti se ìdánwò àsewolé náà. Àyèwò Nígba tí won se àyèwò siwájú síi won rí i pe ìfowosí ìwé náà kìí se ojúlówó on
examine: v; (The doctor was examining the patient.) se àyèwò oní sègùn náà n se àyèwò aláìsàn náà.
examiner: n; (The papers are sent to external examiners.) olùyèwò, olùwadìí wón kó àwon ìwé náà lo fún àwon olùyèwò láti ìta.
example: n; (Can you cite an example.) N jé o lè so àpeere kan.
excel: v; (He tried to excel.) ta yo ; ré kojá ó gbiyanjú àtitayo.
excellence: n; (There is excellence in his work.) ìtayo; ìrékojá. Ìtayo wà nínú isé rè.
excellent: adj; (He provided excellent service.) títayo; dára jùlo ó sètò isé tó dára julo/tó tayo.
except: prep; (We will invite everyone except perhaps martin.) bí ko se pe; àyèfi A ó pe gbogbo ènìyànm ayafi boyá martin
except: v; (Children under five years are excepted from the survey.) yo kúrò wón yo àwon omo tí kò tó odún marun-un kuro nínú ìdiwòn náà.
exception: n; (All students without exception must take the English examination..) ìmúkúrò; ìsátì.Gbogbo akèkòó láìsí imúkúrò ló gbólò se ìdánwò ede Gèésì náà.
exchange: n ; (She is giving me french lessons in exchage for teaching her English.) pàsípààrò ó n kò mi ede faransé ní pàsípààrò fún kíkó tí mo n kó o lédè Gèésì.
exchange: v; (He exchanged the pen for a book.) se pàsípààrò ó se pàsípààrò kálàmù náà fún iwé kan.
excite: v; (The Children were very much excited by the news.) ru sóke –ru ìwúrí/ìfé sókè Ìròyìn náà ru ìfé àwon omo náà sóke gidigidi.
exciting: adj; (The expedition was very exciting.) tí ó dùn móni tàbí tí ó wúni lóri. Ìrìn-àgò náà wúni lórí.
exclaim: v; (‘I don’t understand you’, he exclaimed angrily.) kígbe pèlú ìyàlénu ‘Òrò re ko yé mi’, ó kígbe sókè pèlú ìbínú.
exclamation: n; (Davis gave an exclamation of disgust.) igbe ìyàlénu. Davis kígbe ìyàlénu pé ó sún òun.
exercise: n; (The doctor advised him to take more exercise.) (The story showed considerably exercise of imagination.) (The teacher gave his students an exercise.) ìdárayá onísègùn náà
gbà à ni mòran pé kí ó máa se idáraya dáadáa. Ìlo. Ìtàn náà se àfihàn tí ó je mó ìlò ìwoye. Isé síse: Olùko náà fún àwon akékòó rè ní isé síse.
exercise: v; (He exercises twice a day.) (He exercises his right as a citizen.) sé idárayá ó máa n se ìdáraye léèméji lókúmó. Se ojúse Ó n se ojúse rè gégé bí omo orile-èdè.
exhaust: n; (The smell of the exhaust is not good.) àwon ohun tí a lò tán tí a ti lo ànfaàní tó wà làra rè tán. Òórùn àwon ohun èlò tí a ti lo anfààní ara won tán yen kò dara.
exhuast: v; (She was exhausted by the trip.) (He has exhausted his strength.) mú rè ìrìn náà mú un rè é. Ló párá; lò tán; tán Ó ti lo agbára rè tán.
exhausted: adj; (I am absolutely exhausted.) rè ó ti rè mi pátápátá.
exhaustion: n; (They were in a state of exhaustion after climbing for ten hours.) (There was exhaustion of diesel yesterdat.) àárè. Àárè mú won nígbà tí wón gòkè fún wákàtí méwàá. Ìlògbe Ilogbe opo okò wáyé lánàá.
exhibit: v; (He exhibited the documents a law court.) fi hán; mú wá sí gbangba ó fi àwon iwé náà hàn nílé ejó.
exhibit: n; (Do not touch the exhibits.) (The first exhibit was a knife which the prosecutution claimed was the murder weapon.) àwon nnkan tí
a n se àfihàn won má se fowó kán àwon nnkan tí a n se àfihàn won náà. Erù òfin. Erù ofin àkókó ni òbe kan ìdájó Pè ni ohun ìjà ìpàniyán náà.
exhibition: n; (The was an exhibition of pottery-making yesterday.) àfihàn nnkan. Àfihan ìkòkò síse wáyé lánáà.
exist: v; (The plart exists only in Nigeria.) wà Irúgbìn náà wà ni orílè-ède Nàijírà nnkan.
existence: n; (Do you believe in the existence of the ghonsts?) ìwa; ìwàlàáyè. N jé o gbàgbó nínú ìwáláàyè àwon èmí àìrí?
exit: n; .(To avoid meeting her he made a swift exit.) (There are six exits in the departmental store.) ìjádelo kí ó má bà á pàdé rè ó jé kí ìjáe rè se kánkán ojú ònà àbájade ojú ònà abájáde méfà ló wà ni ilé ìtajà náà.
exit: v; (He exists in the middle of the third secen.) jáde ó jáde ní àárín iran keta eré náà.
expand: v; (The tyre began to expand when they punped air into it.) nà; fè.Táyà náà bèrè sí ní fè nigba tí wón n fé atègùn sí i nínú.
expect: v; (We expected him to arrive yesterday.) reti; dúró dè.A retí rè kó dé lánàá
expedition: n; (They went on an expedition.) ìrìn-àyò.Wón lo nínú ìrìn-àyò
expense: n; (He hired an aeroplane regardless of expense.) ìnáwó ó gba okò bàálù láìwo ti ìnáwó.
expensive: adj; (It is too expensive for me to buy.) wón ó wón jù fún mí láti rà.
experience: n; ìrírí ìrírí ló máa n kó gbogbo wa lógbón.(We all learn by experience
experience: v; (The Child have never experienced kindness.) rí omo náà ko tìí rí àánú gbà rí.
experiment:n; (The researchers are reapeating the experiment on rats.) ìdánwo. Àwon olùwadìí náà n tún ìdánwò náà se lórí àwon eku.
expert: n; (The man is an agricultural expert.) eni tí ó mo nnkan dájú sáká Okùnrin náà mo isé àgbè dájú sákà.
expert: adj; (He is expert cooking good cheap meals.) gbón; mòye ó gbón nínú síse àwon oúnje dáadáa tí ko wón.
explain: v; (He explained his absence.) túmò; fìyè; sàlàyé ó sàlàyé ìdíi rè tí kò fi farahàn.
explanation: n; (He left the room without explanation.) àlàyé ó fí yàrá náà sílè láìsí àlàyé.
explode: v; bú; bé. Adó olóró náà bú.(The bomb exploded
explore: v; (We explore several solution to the problem.) wá kiri. A wá orísìírísìí àwon ònà àbayo fún ìsòro náà.
explosion: n; (The explosion was a mile away.) ìbé; aríwo nlá; ìbú- gbàmù. Ariwo ibúgbàmù náà ju ìbùso kan lo.
express: adj; (He took an expres bus.) yíyára ó wo okò tí o yára.
express: v; (He expressed his opinion.) fi han ó fi ero okàn rè han.
expression: n; (He didn’t notice her expression.) ìsoro; àfihàn ko se akíyèsí àfihàn/ ìsòròo rè.
extend: v; (He extended the programme.) (The extended the road.) lo títí; fà gun ó fa èto náà gùn. Mú gbòòrò Wón mú ònà náà gbòòrò si.
extent: n; (To what extent can he be believed?) ààyè; ibi Títi dé ààyè wo ló le gbàgbo?
extra: adj; (He gave me extra money.) tí ó jé àfokún ó fún ní àfikùn owó
extral: n; (I don’t want you to pay any extra.) afikun. N kò fé kí o san àfikùn kankan.
extra: adv; (It is extra large.) jù, o ti fè jù.
extraordinary: adj; (He told us an extraordinary
story.) tí ó sàjèjí; tí o yani lénu ó so ìtàn to yani lénu fún wa. Tí ó jẹ́ afikun; àfikun. Wón se àfikùn ìpàdè gbogbo-gbòò.
eye: n; (She opened her eyes.) ojú ó la ojú rè.
eye: v; wò, Ó wò mi tìraratìtara (He eyed me curiously.
eyebrow: n; (He plucked his eyebrows.) ìpénpéjú, ó já ìpénpéjùu rè.
eyelash: n; (She was wearing false eyeslashed.) ìrun ojú ó wo àwon ojú tí o jé ìdàrò.
eyepiece: n; (He couldn’t see clearly through the eyepiece.) ìwo ojú ko ríran dáadáa láti inú ìwo ojú naa.