Aminu Ibrahim Daurawa (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kìíní oṣụ̀ kìíní ọdún 1969) tí àwọn ènìyàn tún máa ń pè ní Sheikh Daurawa, jẹ́ onímọ̀ Islam àti ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ìpínlè Kano.[1] Bàbá rẹ̀ ni gbagbúgbajà oníṣẹ́-ìwádìí, ìyẹn Sheikh Ibrahim Muhammad Mai Tafsiri, Sheikh Daurawa èyí ti gómìnà ìpínlè Kano tí í ṣe Abba Kabir Yusuf yàn gẹ́gẹ́ bí commander Hisbah Kano, ní ọdún 2023.[2][3]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
Wọ́n bí i ní ọjọ́ kìíní oṣụ̀ kìíní ọdún 1969, sí agbègbè ìjọba ìbílè Mazugal Dala, ní Ipinle Kano, ní orílè-èdè Nàìjíríà.[4][5]
Ní ọdún 2004, ó lọ sí Bayero University, Kano níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Mass Communication, bí ó ti ẹ̀ jẹ́ pẹ́ kò kẹ́kọ̀ọ́ náà jáde. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí Benin private university, èyí tí ó ní ẹ̀ka ní Kano, àmọ́ kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ níbẹ̀ bákan náà.[6][7][8]
Tún wo
Àwọn ìtọ́kasí