African Action Congress (AAC) jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí Ọmọyẹlé Ṣọ̀wọ̀rẹ́,
olùdásílẹ̀ olùtẹ̀ ìwé-ìròyìn, Sahara Reporters dá silẹ ní Nigeria lọ́dún 2018.[3]
Ọ̀rọ̀-ìmóríwú ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni: Take it back, tí ó túmọ̀ sí gbà á padà. Alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà tí àjọ ìdìbò, INEC mọ̀ lábẹ́ òfin ni Omoyẹlé Ṣòwòrẹ́. [4][5][6] Lọ́jọ́ ajé, ọjọ́ kẹtàlá oṣù karùn-ún ọdún 2019, AAC kéde ìlẹ́lẹ́gbẹ́ Leonard Nzenwa àti ìdádúró ránpé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mìíràn fún ìwà àjẹbánu, ìṣowó báṣubàṣu àti àwọn ìhùwàtako ẹgbẹ́.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí