Abdelmadjid Tebboune (Lárúbáwá: عبد المجيد تبون; ọjọ́ìbí 17 November 1945) ni olóṣèlú ará Algeria tó jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ pé òhun ni Ààrẹ ilẹ̀ Algeria láti December 2019. Ó rọ́pò Ààrẹ Abdelaziz Bouteflika àti Arọ́pò Olórí Orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀ Abdelkader Bensalah. Tẹ́ltẹ́lẹ̀, òhun ló jẹ́ Alákósò Àgbà ilẹ̀ Algeria láti May 2017 di August 2017. Bákannáà, ó tún jẹ́ tẹ́lẹ̀ Alákóso Ètò Ilé láti 2001 di 2002 fún ọdún kan àti ní ẹ̀kan si láti 2012 di 2017 fún ọdún 5.[1]
Itokasi