Ìpínlẹ̀ Adamawa (Fula: Leydi Adamaawa 𞤤𞤫𞤴𞤣𞤭 𞤢𞤣𞤢𞤥𞤢𞥄𞤱𞤢) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Bornosí àríwá ìwọ̀-oòrùn, Gombesí ìwọ̀-oòrùn, àti Taraba gúúsù-ìwọ̀-oòrùn nígbàtí ààlà ìlà-oòrùn rẹ̀ di apákan ààlà orílẹ̀ èdè pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Cameroon. Orúkọ rẹ̀ jẹ yọ látara ìtàn emirate ti Adamawa, pẹ̀lú olú-ìlú ẹ́míréétì tẹ́lẹ̀rí ti Yola tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Adamawa. Ìpínlẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ oríṣiríṣi àkóónú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú áwọn ọ̀wọ́ ẹ̀yà onílùú tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún. Wọ́n dáa sílẹ̀ ní ọdún 1991 nígbàtí ìpínlẹ̀ Gongola tẹ́lẹ̀rí túká di ìpínlẹ̀ Adamawa àti ìpínlẹ̀ Taraba.[3]
Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Adamawa jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ṣùgbọ́n ẹlẹ́ẹ̀kọkàndínlógún ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́rinlé-ní-ìdámẹ́rin gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[4]
Ohun tí a wá mọ̀ sí ìpínlẹ̀ Adamawa ti ní olùgbé láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà pẹ̀lú Bwatiye (Bachama), Bali, Bata (Gbwata), Gudu, Mbula-Bwazza, àti Nungurab (Lunguda) ní àáríngbùngbùn agbègbè náà; Kamwe sí àríwá àti àáríngbùngbùn agbègbè náà; Jibusí gúúsù tí ó naṣẹ̀; Kilba, Marghi, Waga, àti Wula ní ìlà-oòrùn, àti Mumuye ní gúúsù nígbàtí àwọn Fulaniń gbé jákèjádò ìpínlẹ̀ náà lemọ́lemọ́ gẹ́gẹ́ bí darandaran. Ìpínlẹ̀ Adamawa jẹ́ àkóónú oriṣ́iríṣi ẹ̀sìn nígbàtí ìwọ̀n bí 55% àwọn ènìyàn olùgbé jẹ́ Mùsùlùmí Sunni àti ìwọ̀n 30% jẹ́ Kììtẹ́nì (nípàtàkì Lutheran, EYN, ECWA, àti ìjọ aláṣọ ara) nígbàtí àwọn ìwọ̀n 15% jẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀.[5][6]
Imojuto
Agbegbe Ijoba Ibile 21 lowa ni Ipinle Adamawa :
Itokasi